Awọn agbebọn tun ti ji awakọ bọọsi kan atero inu ẹ gbe loju-ọna Ifẹ si Ibadan

Florence Babaṣọla

Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, la gbọ gbe awọn agbebọn da ọkọ bọọsi akero kan duro nitosi Waasinmi, loju-ọna Ifẹ si Ibadan, wọn mu awakọ naa ati ero kan ṣoṣo to wa ninu ẹ.

Ibọn ti wọn yin soke lo fu awọn ọlọpaa ti wọn wa lorita kan nitosi ibẹ lara, bayii ni wọn bẹrẹ si i yinbọn si awọn agbebọn ọhun, ṣugbọn wọn ji awọn eeyan naa gbe gba inu igbo kan lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn agbofinro ti wa ninu igbo naa lati gba awọn ti wọn ji silẹ.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe awọn afurasi mẹta lọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply