Awọn agbebọn tun ti ji awọn arinrin-ajo gbe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Awọn ọlọpaa, ọlọdẹ atawọn ajijagbara Kiriji ti bẹrẹ wiwa awọn arinrin-ajo ti awọn agbebọn ji gbe lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lagbegbe Odo Ọṣun, niluu Imẹsi-Ile, nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi awọn araalu naa to ba Alaroye sọrọ ṣe sọ, ipinlẹ Ekiti lawọn arinrin-ajo naa ti n bọ, ki awọn agbebọn naa too da wọn duro nigba ti wọn fẹẹ kọja si ọna Ila.

Ko sẹni to mọ iye awọn arinrin-ajo ti wọn ji gbe ninu mọto naa, ṣugbọn gbogbo wọn la gbọ pe wọn ji ko wọnu igbo lọ.

Alakooso Kiriji Heritage Defenders, Dokita Ademọla Ẹkundayọ, ṣalaye pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn ọmọ ẹgbẹ Kiriji ti ya wọnu igbo lati ṣawari awọn arinrin-ajo naa.

Ẹkundayọ sọ pe lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ Kiriji ti bẹrẹ wiwa naa ni awọn ọlọdẹ atawọn ọlọpaa darapọ mọ wọn ninu igbo.

Iwadii fihan pe ẹnikan ti lọ si agọ ọlọpaa ilu naa lati sọ fun wọn pe araale oun wa lara awọn arinrin-ajo ti wọn ji gbe ọhun.

Gbogbo iyanju lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun sọrọ lo ja si pabo nitori foonu rẹ ko lọ, bẹẹ ni ko si fesi si atẹjiṣẹ ti akọroyin wa fi ranṣẹ si i lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply