Awọn agbebọn ya bo ṣọọṣi Sẹlẹ ni Mowe, wọn ji eeyan meji gbe lọ

Faith Adebọla

Atẹgun iṣẹlẹ ijinigbe to n fẹ yika orileede yii ti tun wọ ipinlẹ Ogun bayii, awọn agbebọn kan ni wọn ya bo ṣọọṣi ijọ Sẹlẹ, Celestial Church of God, to wa niluu Mowe, nitosi aala ipinlẹ Ogun ati Eko, ti wọn si ji meji ninu awọn olujọsin ṣọọṣi naa gbe wọ’gbo tẹnikẹni ko ti i mọ di ba a ṣe n sọ yii.

Orukọ awọn ti wọn ji gbe ọhun ni Ṣeyifunmi Ọladapọ ati Abiọla Olubọboye.

Irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, ọsu Kẹta, ọdun yii, niṣẹlẹ buruku naa waye.

Ninu alaye ṣoki ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun gbe soju opo ayelujara wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, wọn ni adugbo kan ti wọn n pe ni Oriyanrin, niluu Mowee, ni ṣọọṣi Sẹlẹ naa wa, ibẹ ni wọn ti n ṣe ṣe isin wọn, kawọn agbebọn ti wọn ju dọsinni kan lọ, ti wọn si dihamọra pẹlu nnkan ija oloro bii ibọn too ya bo wọn.

Inu igbo kijikiji kan to wa lagbegbe ọhun ni wọn lawọn agbebọn naa poora si pẹlu awọn ti wọn ji gbe.

Ṣa o, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Abiọdun Alamutu, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ gbogbo fọn ka sagbegbe naa, ki wọn si wa amookunṣika ẹda naa lawaari

Leave a Reply