Nitori bi ita ṣe ri, obinrin ara Amẹrika yii dana iṣinu aawẹ fawọn Musulumi n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Latari ọwọngogo ounjẹ to gbode, paapaa ju lọ lasiko aawẹ Ramadan yii, obinrin ara ilẹ Amẹrika kan to jẹ ẹlẹsin Kirisitẹni, to tun jẹ obinrin akọkọ to n wakọ tirela nilẹ Amẹrika, Amọpe Philips, ti bẹrẹ si i dana, to si n pin ounjẹ iṣinu aawẹ fawọn Musulumi lagbegbe Ajíbẹ́sin, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

L’Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ALAROYE ṣabẹwo si agbegbe Ajíbẹ́sin, nibi ti awọn aafaa ti Amọpe gbe eto pipin ounjẹ naa le lọwọ ti n dana ẹkọ ati ọlẹlẹ, ti wọn si n pin in fawọn araalu.

Gẹgẹ bi awọn olugbe agbegbe naa ṣe sọ, wọn ni wọn pin ounjẹ tutu, wọn si tun n dana iṣinu fun gbogbo awọn olugbe agbegbe naa, eyi ti wọn ni obinrin ọmọ bibi ilu Eruwa, nipinlẹ Ọyọ, ọhun ṣagbatẹru rẹ.

Lara awọn aafaa ti wọn gbe eto naa le lọwọ to ba ALAROYE ṣọrọ, Aafa Kamaldeen, sọ pe erongba ti obinrin ẹlẹyin ju aanu yii fi gbe eto naa kalẹ ni lati maa fun awọn to ku diẹ kaato lounjẹ iṣinu aawẹ, ṣugbọn ki i ṣe inu aawẹ nikan, wọn ni ki i aawẹ too de ni awọn ti n pin ounjẹ naa.

O tẹsiwaju pe ki i ṣe ẹlẹsin Musulumi nikan ni awọn n fun lounjẹ, ati Musulumu ati Onigbagbọ, to fi mọ ẹlẹsin abalaye, ni wọn n jẹ ninu anfaani ounjẹ ọhun. O ni ounjẹ tutu ati ṣiṣe ni awọn n pin, bi awọn ṣe n pin irẹsi lawọn n pin sẹmo, ẹwa ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni okere tan eeyan ọọdunrun ni awọn n fun ni ounjẹ lojoojumọ latigba ti aawẹ Ramadan ti bẹrẹ titi di asiko yii.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o parọwa si gbogbo awọn tori ṣẹgi ọla fun lawujọ lati fi ti Amọpe yii ṣe arikọṣe, ki wọn maa ṣaanu awọn mẹkunnu, ki wọn kan ma maa pariwo ijọba nikan. O ni ẹlomiiran ni ounjẹ eeyan mẹwaa ninu ile ti wọn tilẹkun mọ ọn lai fi ṣe aanu.

Ọkan lara awọn to n jẹ anfaani ounjẹ ti wọn n pin ọhun, Arabinrin Kẹhinde Alabi, sọ pe eto to dara ni eto naa, ti Ọlọrun si nifẹẹ si i pẹlu, ati pe idunnu nla ni fun gbogbo awọn tawọn n jẹ anfaani eto naa, nitori pe ẹni to ba rọwọ mu lọ sẹnu lasiko ọwọngogo ounjẹ yii yoo fogo fun Ọlọrun.

 

Leave a Reply