Ọwọ tẹ Mustapha to n ta ibọn fawọn ọdaran

Adewale Adeoye

Ọkan pataki lara awọn to n ta ibọn fawọn ọdaran laarin ilu Mandela, nijọba ibilẹ Minna, nipinlẹ Niger, Ọgbẹni Mustapha Ishaku, lọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa ti tẹ bayii. Ọdọ wọn lo wa to ti n ran wọn lọwọ lati mu awọn onibaara rẹ gbogbo ti wọn n ra awọn ohun ija oloro ọhun lọwọ rẹ.

ALAROYE gbọ pe aipẹ yii lawọn ọlọpaa lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ lẹyin tawọn owuyẹ kan waa ta wọn lolobo nipa iṣẹ to lodi sofin to n ṣe laarin ilu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Wasiu Abiọdun, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ nibi to n gbe, ti wọn si ju u sahaamọ wọn fohun to ṣe.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ sọ pe, ‘’Ọdọ wa ni Mustapha Ishaku, ẹni ọdun mọkanlelogun kan to n gbe lagbegbe Kuta, nijọba ibilẹ Shiroro, wa bayii, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn ọlọpaa lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ lẹyin tawọn owuyẹ kan waa fi to wa leti pe o n ta ibọn fawọn ọdaran laarin ilu. Oriṣiiriṣii ibọn atawọn ohun ija oloro la ba nile rẹ lasiko ta a lọọ ba a. Agbegbe Mandela, nijọba ibilẹ Minna, la ti mu un, irọ to pa fawọn ọlọpaa ni pe ọdẹ loun, ati pe iṣẹ ọdẹ loun n lo awọn ibọn naa fun.

‘‘Ṣugbọn nigba tawọn ọlọpaa n fọrọ wa a lẹnu wo, o jẹwọ pe iṣẹ awọn to n jo irin, iyẹn wẹda loun n ṣe tẹlẹ, pe Ọgbẹni Bala kan tawọn ọlọpaa ti kede rẹ bayii gẹgẹ bii ọdaran lo maa n rọ ibọn ọhun, toun aa si ṣe iyooku ko too di pe awọn ta a fawọn to nilo rẹ lowo pọọku’’.

Alukoro ni ibọn ogun lawọn eeyan naa ti ta sita fawọn onibaara wọn gbogbo. O pari ọrọ rẹ pe awọn maa too fọwọ ofin mu Bala ti i ṣe ọrẹ Mustapha, tawọn si maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii.

Leave a Reply