Ezekiel, ọmọ ọdun mẹwaa, pa ọrẹ rẹ lasiko ti wọn n gba bọọlu l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ejigbo, nipinlẹ Eko, ni ọmọ ọdun mẹwaa kan, Evbota Ezekiel, to pa ọrẹ rẹ, Oloogbe Israel Ogunlẹyẹ, ẹni ọdun mẹwaa, wa bayii, nibi to ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni oloogbe naa n gba bọọlu lẹgbẹẹ ṣọọbu iya rẹ to wa lagbegbe Oluwọle Powerline, niluu Ejigbo, nipinlẹ Eko, lojiji ni ariyanjiyan nla kan ṣẹlẹ laarin oun ati Ezekiel, ti iyẹn si fun un lọrun titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ patapata lọjọ naa. Bi oloogbe naa ti ku tan ni awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n gba bọọlu ti sa lọ.

ALAROYE gbọ pe baba oloogbe naa lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti, tawọn yẹn si tete lọọ fọwọ ofin mu Ezekiel nile awọn obi rẹ lati beere ọrọ lọwọ rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe kayeefi nla ni ọrọ ọhun jẹ fawọn, ati pe awọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si ileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Isọlọ, tawọn si maa ṣayẹwo sokuu rẹ lati mọ ohun to pa a gan-an.

Leave a Reply