Ọpẹyẹmi tan ọrẹ ẹ lọ sinu igbo, lẹyin to pa a tan lo ji ọkada rẹ gbe lọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin kan, Dọlapọ Babalọla, lori ẹsun ṣiṣeku pa ọrẹ rẹ, Ọpẹyẹmi Oyelakin. Lẹyin to pa a tan lo tun ji ọkada rẹ gbe sa lọ.

ALAROYE  gbọ pe lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni wọn ti n wa ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ọhun. Nigba tawọn ẹbi rẹ wa a titi ti wọn ko si le sọ pato ibi to wọlẹ si ni wọn lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Lẹyin bii ọsẹ kan gbako tawọn ọlọpaa ti n fimu finlẹ lori ibi ti ọkunrin yii wọlẹ si lọwọ tẹ Dọlapọ to jẹ ọrẹ timọtimọ rẹ, ti wọn si mu ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji naa lọ si agọ wọn lati fọrọ wa a lẹnu wo.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun un lo ti pada jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun mọ nipa iku Ọpẹyẹmi, oun lo si ṣaaju Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo atawọn ọmọọṣẹ rẹ lọ sinu igbo kan to wa niluu Oke-Igbo, nijọba ibilẹ Ilẹ-Oluji/Oke-Igbo, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, lati lọọ fi ibi to sin oku ọmọ ọlọmọ si lẹyin to pa a tan han wọn.

Afurasi apaayan ọhun sọ ninu alaye to ṣe pe ọrẹ timọtimọ loun ati Ọpẹyẹmi tẹlẹ, ọdun mẹjọ sẹyin lo ni awọn ti rira gbẹyin, ko too di pe awọn mejeeji tun pade ara awọn nibi kan niluu Ondo, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta yii.

Lọjọ keji lo pe ọrẹ rẹ yii pe ko waa fi ọkada rẹ gbe oun ni agbegbe Oke-Agunla, l’Ondo, ki awọn le jọ lọọ ri ọrẹ oun kan to n jẹ Mufutau Sikiru ni Sabo, Ondo.

Bi wọn ṣe n de Sabo ni Dọlapọ ati Sikiru to jẹ ẹnikeji rẹ ninu iwa ọdaran ti gbimọ-pọ, ti wọn si ni ki Ọpẹyẹmi maa gbe awọn lọ sinu igbo kan niluu Oke-Igbo, lati lọọ fi oko to loun fẹẹ maa da han an.

Bi wọn ṣe de inu igbo ọhun tan lawọn mejeeji yiju pada si ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa, ti wọn si n tiraka lati ja ọkada rẹ gba lọwọ rẹ, ki wọn le gbe e sa lọ.

Ibi to ti n du ọkada yii mọ wọn lọwọ ni Dọlapọ ti lọọ gbe okuta nla kan, eyi to la mọ ọrẹ rẹ lori, tiyẹn si gba ibẹ ku loju-ẹsẹ.

Wọn jawe bo oku rẹ mọlẹ ninu igbo nibẹ, wọn si gbe ọkada ọkunrin naa lọọ ta fun onibaara wọn kan to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni ẹgbẹrun lọna aadoje Naira (#130, 000).

Dọlapọ ni lati ọdun 2021 loun ti yan iṣẹ ọkada jijagba laayo, ati pe, o kere tan, ọkada bii mẹẹẹdogun loun nikan ti ja gba lọwọ awọn to ni in.

Lara awọn ilu to ni oun ti n ṣọṣẹ ni: Akurẹ, Ondo, Ileṣa, Ilẹ-Ifẹ ati ipinlẹ Ekiti. O ni oun ko paayan ri lawọn ibi ti oun ti lọọ ṣiṣẹ sẹyin ko too di pe ọrọ ti Ọpẹyẹmi sẹlẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Ọladipọ, sọ pe iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori bọwọ ṣe fẹẹ tẹ Sikiru to jẹ ẹnikeji Dọlapọ, ki awọn mejeeji le jọ jiya to tọ labẹ ofin.

Abayọmi ni arọwa oun si awọn ọlọkada ni lati maa fura nigbakuugba ti ẹnikẹni ba bẹ wọn lọwẹ lati gbe oun wọ’nu igbo tabi ibi to ba ti dakẹ rọrọ lọ.

Ọkan ninu awọn ẹbi Oloogbe, Pasitọ Taiwo Oyediran, ni ko ti i pẹ rara ti Ọpẹyẹmi ko wa siluu Ondo lati Ibadan to n gbe tẹlẹ lati waa tẹsiwaju ninu iṣẹ ọkada to n ṣe, ko too waa ko agbako iku ojiji lati ọdọ ẹni to pe ni ọrẹ rẹ yii.

O ni iyawo ati ọmọ kan ni oloogbe ọhun fi saye lọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn lawọn agbofinro gbe oku Dọlapọ kuro ninu igbo ti wọn pa a si lati bii ọjọ mẹrinla sẹyin lati lọọ tọju rẹ pamọ si mọṣuari.

 

Leave a Reply