Nitori obinrin, ṣọja gun ọmọkunrin yii pa m’ọnu ṣọọbu rẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọkunrin oniṣowo kan, Ezeani Ebuka, ni ṣọja kan ti gun lọbẹ pa mọ’nu ṣọọbu rẹ to wa ni Iyana Òkè-Àró, Arakalẹ, niluu Akurẹ, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ lati ẹnu ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ni ọkunrin ṣọja ti ko wọṣọ ọhun wa si ṣọọbu kan to wa lẹgbẹẹ Ebuka, lati ra kapẹẹti.

Lojiji lawọn ọlọja to wa nitosi ṣakiyesi pe ariyanjiyan deedee bẹ silẹ laarin ṣọja ọhun ati obinrin to fẹẹ ra kapẹẹti lọwọ rẹ. Ibi to si ti fẹẹ maa lu obinrin to n t’ọmọ lọwọ naa ni Ebuka ti da si i nigba ti ara rẹ ko gba a mọ. Ṣugbọn kia ni ṣọja naa ti fi onija rẹ silẹ, to si gba ya Ebuka.

O ni nigba to ya ni ọkunrin ologun naa taka si i, o ni ko maa reti oun pada laipẹ. Bo ṣe binu gun ọkada to gbe wa sibẹ niyẹn, to si ba tirẹ lọ.

Gbogbo ero awọn to wa nibẹ ni pe ọrọ naa ti tan sibẹ, afi bo ṣe di aarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, ti ṣọja naa tun pada wa loootọ pẹlu ọbẹ daga kan lọwọ rẹ, to si bẹrẹ si i gun Ebuka nikun titi ti iyẹn fi ṣubu lulẹ ninu agbara ẹjẹ, ti ko si le dide mọ.

Lẹyin eyi lo too fi i silẹ, to si sa kuro nibẹ kawọn eeyan too de.

Awọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun du ẹmi rẹ pẹlu bi wọn ṣe sare gbe digbadigba lọ sileewosan ijọba to wa l’Akurẹ, ṣugbọn ti wọn ko ri i gbe de ọsibitu naa to fi ku mọ wọn lọwọ.

Eyi lo ṣokunfa b’awọn oniṣowo to jẹ ẹgbẹ oloogbe ọhun ṣe tu jade lati fẹhonu han, ati lati beere fun idajọ ododo lori iku ọkan ninu wọn ti ṣọja pa nipakupa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun 32 Atilẹri to wa l’Akurẹ leti, ki wọn le ṣawari ṣọja naa lati le waa foju wina ofin.

 

Leave a Reply