Eyi lohun to wa laarin emi ati Olubadan to waja- Ọbasanjọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Yatọ si pe “Ẹgbọn mi”, “Ẹgbọn mi” l’Olubadan to waja, Ọba Mohood Ọlalekan Balogun, maa n pe aarẹ orileede yii ni nigba kan ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, baba naa ti ṣalaye pe ibaṣepọ to wa laarin oun pẹlu ọba to wọ kaa ilẹ lọ naa ju eyi to han si ọpọ eeyan lọ.

Lasiko abẹwo to ṣe si idile Ọba Balogun nile ẹ to wa laduugbo Alarere, n’Ibadan, lo ti ṣafihan ibaṣepọ rẹ pẹlu oloogbe naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Ọbasanjọ, ẹni ti ọrẹ ẹ, Ọtunba Oyewọle Faṣawẹ; ati Ọnarebu Gbenga Adewusi, ti i ṣe alakooso agba fun ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Ọyọ, iyẹn 3SC, nigba kan ri, kọwọọrin pẹlu ẹ sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ bi oun pẹlu Ọba Balogun ṣe sun mọ ara awọn to.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Abẹwo ti mo ṣe si idile oloogbe yii jẹ ohun to pọn dandan fun mi lati ṣe, nitori Kabiesi ki i ṣe àjèjì si mi, ọrẹ mi ni wọn jẹ.

“Ọba Balogun lo ipo wọn daadaa, wọn mu apọnle ati iyi ba ipo ọba nigba ti wọn wa lori itẹ. Kabiesi gan-an la ba maa pe ni “Gbọ́baníyì”.

Lẹyin naa lo di ọkan ninu awon ọmọ oloogbe to gba a lalejo lọwọ mu, to si ba a sọrọ gẹgẹ bii baba ṣọmọ.

Ọbasanjọ ṣalaye siwaju pe, “O wu wa ki Ọba Balogun wa pẹlu wa ṣiwaju si i, ṣugbọn ọba Alápadúpẹ́ l’Ọlọrun, bi Kabiesi ko ba waja lasiko yẹn, to ba jẹ pe àrà ti ko dun mọ wa ninu l’Ọlọrun fi wọn da nkọ?

“Ki i ṣe bi nnkan ba ṣe pọ to lo ṣe Pataki, bi ko ṣe bi nnkan ba ṣe ṣanfaani to. Igbesi aye to nitumọ ni Kabiesi gbe laye. Iwọnba asiko ti wọn si lo ori itẹ, gbogbo aye lo mọ ọn si rere”.

Ẹkẹrin Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Amidu Ajibade; Alhaji Tajudeen Arẹmu, to tun ti figba kan ri jẹ olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Ọyọ; meji ninu awọn ayaba Olubadan to waja, Olori Ọlayinka pẹlu Olori Olufunmilayọ, ati diẹ ninu awọn ọmọ oloogbe naa ni wọn gba aarẹ ana naa pẹlu atwọn eeyan ẹ lalejo.

Nigba to n fi idunnu ẹ han nipa abẹwo naa,

Ọba Ajibade, ti i ṣe Ẹkẹrin Olubadan, ṣapejuwe Ọbasanjọ gẹgẹ bii ọrẹ tootọ, paapaa, pẹlu bi ọkunrin naa ṣe wa lara awọn eeyan pataki nilẹ yii to ṣabẹwo si oloogbe lasiko to n mura lọwọ lati gori apere ọba, to si tun waa ṣabẹwo si idile ọba naa lẹyin to dagbere faye tan.

O waa rọ aarẹ ana naa lati ma ṣe jẹ ki abẹwo rẹ mọ ni tọjọ naa nikan, bi ko ṣe pe ko maa bẹ wọn wo bẹẹ lẹẹkọọkan.

Ninu ọrọ tiẹ, Bọbajiroro ilẹ Ọba, Alhaji Tajudeen Arẹmu, to tun ti figba kan jẹ olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Ọyọ, ṣapejuwe Ọbasanjọ gẹgẹ bii ọrẹ otitọ, to ṣoju, to tun ṣẹyin.

O ni, “bo ba ṣe pe Kabiesi ṣi wa laye ni, a ba ni boya nitori anfaani to ṣee ṣe kẹ ẹ ri lara wọn lẹ ṣe wa, ṣugbọn Kabiesi ti ṣalaisi bayii, wọn o si nipo lati ṣe ẹnikẹni loore mọ. Iyẹn la ṣe mọ riri wiwa tẹ ẹ wa yii”.

Leave a Reply