Kindinrin eeyan mẹta, ọkan mẹta, eegun ẹyin ati ahọn ni wọn ba lọwọ Aafaa Idris l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Aafaa kan ti wọn porukọ rẹ ni Oluwafẹmi Idris, lọwọ ti tẹ l’Akoko, nipinlẹ Ondo, pẹlu ọpọlọpọ awọn ẹya ara eeyan ti wọn ka mọ ọn lọwọ.

Ni ibamu pẹlu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, lo ti sọ pe lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lawọn eeyan kan ti waa ta awọn lolobo pe Idris, ẹni tọpọ eeyan mọ si Aafaa, ko awọn ẹya ara eeyan kan pamọ sile rẹ, eyi to ṣee ṣe ko fẹẹ fi ṣetutu.

O ni latigba naa lawọn ti n ṣọ ọ, titi tawọn fi de ile rẹ nibi kan l’Akoko, ti awọn ko ti i fẹẹ darukọ, nitori iwadii to ṣi n lo lọwọ, nibi ti awọn ti ṣawari awọn ẹya ara eeyan bii kindinrin mẹta, ọkan eeyan mẹta, eegun ẹyin ati ahọn eeyan.

Ọdunlami ni Idris fidi rẹ mulẹ ninu alaye to ṣe fawọn lasiko ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe Aafaa Musulumi loun, o ni ọrẹ oun kan ti oun mọ si Alaaji, ẹni ti awọn jọ jẹ Aafaa ati ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Kutelu, ni wọn waa ko awọn ẹya ara eeyan naa fun oun.

Alukoro ni Aafaa Idris tun jẹwọ pe oun naa ta ori eeyan mẹta fun ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Babatunde Kayọde, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Oluwo.

O ni Idris ati Oluwo ti wa nikaawọ awọn, bẹẹ ni iwadii n tẹsiwaju lati ri awọn yooku mu.

 

 

Leave a Reply