Wahab yii ma laya o, ọlọpaa lo fẹẹ ja lole ti wọn fi mu un

Adewale Adeoye

Afurasi adigunjale kan, Akinjọbi Wahab, ẹni ọdun mọkandinlogun, ti ṣi iṣẹ ṣe bayii o. Ọlọpaa ti ko wọsọ lo fẹẹ ja lole ti wọn fi mu un. Ṣe oun ko kuku mọ pe agbofinro ni wọn, nitori wọn ko wọsọ iṣẹ. Ni nnkan bii aago mẹrin aarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, yii, lọwọ ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa, ‘Rapid Response Squad’ (RRS), ẹka tipinlẹ Eko tẹ ẹ lagbegbe Acme, ni Agidingbi, niluu Ikẹja, lasiko to fẹẹ ja ọlọpaa kan ti ko wọ’ṣọ ijọba sọrun lole ọkada tiyẹn n gun lọ jẹẹjẹ rẹ.

ALAROYE gbọ pe aipẹ yii ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, C.P Adegoke Fayọade, pa a laṣẹ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, paapaa ju lọ, lagbegbe Agidingbi, niluu Ikẹja, pe ki wọn gba iwa laabi atawọn afurasi ọdaran gbogbo wọlẹ patapata lagbegbe naa. Lara ohun ti wọn si ni ki wọn maa ṣe ni pe ki wọn maa lọ kaakiri igberiko lati fọwọ ofin mu awọn oniṣẹ ibi to n lo ayika naa fun iṣẹ buruku.

Ẹnu iṣẹ ilu ni ọlọpaa ọhun wa to n gun ọkada rẹ lọ, ti ikọ jaguda ẹlẹni mẹrin kan yọ ọ si lojiji, Wahab lo ṣaaju ikọ ọhun pẹlu ada oloju meji lọwọ rẹ, wọn fẹẹ ja ọkada ọhun gba mọ ọlọpaa naa lọwọ. Ṣugbọn agbofinro yii fi ajulọ han wọn, ọwọ tẹ Wahab, ṣugbọn awọn ẹgbẹ rẹ yooku raaye sa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, sọ pe laipẹ yii lawọn maa foju Wahab bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba ri awọn yooku rẹ mu tan.

Leave a Reply