Wọn ti mu Balogun o, ayederu ṣọja to n faṣọ ijọba lu jibiti l’Ekoo

Adewale Adeoye

Lagbegbe Isheri-Ọṣun, nipinlẹ Eko, lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ayederu ṣọja kan to pe ara rẹ ni Sajẹnti Major Fẹmi Balogun, pẹlu aṣọ ijọba lọrun rẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni awọn ọlọpaa kan n lọ kaakiri, ti wọn si ri ayederu ṣọja ọhun to jẹ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede Nigeria ti n wa a tẹlẹ fawọn oniruuru ẹsun iwa ọdaran lagbegbe Fagbile Estate, niluu Ijegun, nipinlẹ Eko. Agbegbe yii kan naa lo jẹ pe ibẹ lawọn ọdaran ti maa n fọ agba epo bẹntiroolu nigba gbogbo. Nigba to de ọdọ awọn ọlọpaa naa jẹwọ pe loootọ, ayederu ṣọja loun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ọjọ pẹ tawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii ti n wa a, ko too di pe wọn gba a mu lagbegbe Ijegun, lagbegbe t’awọn ọdaran ti maa n bẹ ọpa epo bẹntiroolu nigba gbogbo.

O ni loju-ẹsẹ tawọn ti fọwọ ofin mu un lo ti ni kawọn ọlọpaa ṣ’oun jẹẹjẹ.

Alukoro ni laipẹ yii lawọn maa ba a ṣẹjọ lori iwa to hu.

 

Leave a Reply