Nibi ti ọmọkunrin yii ti n mura ati se ẹran ẹlẹran to ji gbe lawọn ọlọpaa ti mu un

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Kurikyo, nijọba ibilẹ Lafia, nipinlẹ Nasarawa, ni Ọgbẹni Mohammed Tanko, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o lọọ ji ẹran agbo nla kan gbe laarin ilu wa bayii.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Anguwan Gayam, ni afurasi ọdaran ọhun n gbe, ṣugbọn to lọọ ṣagbegbe Kurikyo, lati lọọ ji ẹran agbo nla kan gbe lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Gbara to gbe ẹran agbo ọhun dele rẹ lo ti du u lọbẹ, nibi to ti n ṣe aayan lati se e lawọn ẹni to lẹran ti mu ọlọpaa waa ba a, wọn fọwọ ofin mu un loju-ẹsẹ, ti wọn si ti i mọle.

Ọdọ awọn ọlọpaa ti Tanko wa lo ti jẹwọ fun wọn pe loootọ, ohun ti oun ṣe ko daa rara, ṣugbọn bi ilu ṣe le koko bii oju ẹja lo sun oun debi iwa palapala naa.

Awọn ọlọpaa ti lawọn maa too gbe Tanko lọ si kootu, ko le lọọ ṣalaye ara rẹ fun adajọ ile-ẹjọ tawọn maa foju rẹ ba.

Leave a Reply