Adewale Adeoye
Pẹlu ọrọ ti Abilekọ Abọsẹde Adeyẹmọ, iya to bi gbajumọ akọrin nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, sọ laipẹ yii, o daju pe ọrọ ayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe naa ṣi maa bi ige ati adubi, nitori pe iya oloogbe naa ti sọko ọrọ sawọn ọmọ orileede Naijiria ti wọn n sọ ọriṣiiriṣii nnkan nipa rẹ pe ki wọn fi tiwọn ṣe tiwọn. O ni ọrọ ayẹwo ẹjẹ ọmọ oloogbe naa ki i ṣe ti taja tẹran, laarin ẹbi awọn lọrọ naa gbọdọ wa. Bakan naa lo sọ ọ di mimọ pe bi asiko ba to, o di dandan ki Wunmi ṣe ayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Emi paapaa ni mo sọ pe ki Alagba Joseph Alọba ti i ṣe Baba Mohbad ṣe ayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe ṣaaju akoko yii, ko sohun to kan awọn ọmọ orileede Naijiria nipa ba a ṣe fẹẹ ṣe ayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe rara, laarin idile wa nikan lọrọ ayẹwo ẹjẹ ọhun gbọdọ wa, ko kan ẹnikankan. Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba oloogbe lo fọ gbogbo ọrọ ọhun loju pata, emi paapaa fara mọ pe ko ṣe e.
‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, ko sẹnikan to ri aarin Wunmi ati Alagba Joseph Alọba tẹlẹ, iyawo ọmọ rẹ ni, wọn nifẹẹ sira wọn tẹlẹ, mi o mọ idi ti ko ṣe le ba a sọrọ nipa ayẹwo ẹjẹ ọhun ki wọn si jọ ọ fẹnu ko sibi kan naa, ṣe oloogbe tiẹ jiyan pe ki i ṣe oun loun bi Liam nigba to wa laye ni, ọmọ to jẹ pe ṣe ni inu Baba Mohbad maa n dun si i nigba gbogbo pe oun naa ri ọmọọmọ oun laye. Aimọye nnkan to daa lo ti sọ nipa Liam nigba ti oloogbe wa laye, o ṣe waa jẹ nigba to ku tan lo n pe e lọmọ ale bayii.
‘‘Emi paapaa n wa idajọ ododo lori iku ọmọ mi, ṣugbọn ki i ṣe nipasẹ ọna ti Alagba Joseph Alọba n gbe ọrọ naa gba bayii. Awọn ọmọ orileede Naijiria mọ ootọ nipa iṣẹlẹ ọhun, ko yẹ ka da ọrọ ayẹwo ẹjẹ f’ọmọ oloogbe mọ ija iku Mohbad ta a n gbe rara, idi ree ti mo fi n ba baba rẹ ja lori ọwọ to fi mu iku oloogbe naa bayii.
‘’Ohun ti ko ye mi nipa ọrọ ọhun ni pe, bawo ni Alọba ti i ṣe baba oloogbe ṣe maa koriira Liam to bayii, bẹẹ mo bẹ ẹ pe ko ṣaforiji fun Wunmi bi ọmọ naa ba ṣẹ ẹ, ki wọn si pari gbogbo ija to wa laarin wọn. Bawo ni ọkunrin naa ṣe maa ṣe ohun gbogbo ni wadu-wadu bayii, to si n sọ pe oun n wa idajọ ododo fun oloogbe. Alọba ti gbagbe pe lọjọ kan, gbogbo wa pata n pada lọọ sibi ti oloogbe wa bayii. Joseph Alọba kan n lo iku oloogbe lati pawo sapo ara rẹ lasan ni, laipẹ yii, oju rẹ aa ja.’’