Eedi ree o! Ibọn ọlọdẹ ṣeeṣi yin, o pa ọmọde mẹta, awọn mẹrin wa nileewosan

Adewale Adeoye

Awọn ọdọmọde mẹta lo ku, awọn mẹrin mi-in fara pa yannayanna lasiko ti ibọn ọlọdẹ kan ṣeeṣi yin ba wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ninu oko kan to wa lagbegbe Didango-Gaita, nijọba ibilẹ Karim Lamido, nipinlẹ Taraba.

Awọn mẹta ti wọn pade iku ojiji lasiko ti ibọn ọhun yin ni: Miracle Danjuma, ọmọ ọdun mọkanla, Liyacheyan Bitrus, ọmọ ọdun mejila ati Kefas Bitrus, ọmọ ọdun mọkanla.

ALAROYE gbọ inu oko irẹsi ti wọn ko awọn ọmọ ọhun lọ ni wọn ti n fibọn baba wọn ṣere, lojiji ni ọkan lara awọn ọmọ ọhun ṣeeṣi fa oko ibọn naa, to si yin in pa mẹta danu lara awọn ẹlẹgbẹ ẹ to wa lori igi, nigba tawọn mẹrin kan to wa nilẹ fara pa yannayanna lọjọ naa.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P David Iloyonomon, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ko sootọ kankan ninu pe awọn agbebọn kan ni wọn waa kogun ja awọn araalu naa tabi pe bọnbu ni wọn ju sọdọ awọn ọmọ ọhun gẹgẹ bii ahesọ tawọn kan n gbe kiri.

O ni, ‘‘Lẹyin ta a ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun daadaa, ẹri to daju ṣaka wa pe ki i ṣe bọnbu tabi pe awọn agbebọn kan lo waa ṣọṣẹ fawọn araalu naa gẹgẹ bi iroyin ẹlẹjẹ kan to n lọ kaakiri igberiko nipa iṣẹlẹ ọhun. Loju-ẹsẹ ta a ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun la ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ sita, tawọn yẹn si ti jabọ pe ki i ṣe bọnu rara, ibọn ọdẹ kan lo ṣeeṣi yin mọ awọn ọmọde naa lọwọ lasiko ti wọn fi n ṣere, awọn ọmọde mẹta lo ku loju-ẹsẹ nigba ti ibọn naa yin mọ wọn loju lori igi ti wọn wa. Awọn mẹrin ti wọn wa nisalẹ ṣeṣe gidi, wọn si ti n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa bayii.

Ọga ọlọpaa waa rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn maa ri i daju pe wọn fidi ootọ mulẹ daadaa ko too di pe wọn waa fọrọ to awọn leti.

 Orukọ awọn to fara pa ni Joseph Danjuma ọmọ ọdun mẹjọ, Leah Aluda ọmọ ọdun mẹjọ, Godbless Hassan, ọmọ ọdun meje ati Christian Hassan, ọmọ ọdun meje. Gbogbo wọn ni wọn wa nileewosan ti wọn ti n gba itọju.

Leave a Reply