Wọn ti mu Adamu o, maaluu mẹtalelogun lo lọọ ji ko

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Gombe, ti tẹ afurasi ọdaran kan, Adamu Maikudi, ẹni ọdun mẹtalelogun, to wa lati abule Mai Rana, ijọba ibilẹ Billiri, nipinlẹ Gombe, nitori maaluu onimaluu to ji ko.

Abule Golombi, nijọba ibilẹ Shongom, nipinlẹ Gombe, ni afurasi ti lọọ ji maluu mẹtalelogun to jẹ ti Ọgbẹni Anchau Maishanu, toun pẹlu awọn meji kan ti wọn ti sa lọ jọ lọọ ji ta.

Ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Gombe, ti wọn ti foju awọn ọdaran naa hande ni Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, ASP Mahid Abubakar, ti ṣalaye ọna ti wọn gba mu afurasi ọhun.

Abubakar ni, “Maishanu lo waa fẹjọ sun ni teṣan Pero Chonge, pe afurasi mẹta kan, to fi mọ Maikudi tawọn ọlọpaa ri mu, lẹdi apo pọ laarin ara wọn lati ji maaluu oun labule Golombi, ti wọn si lọọ ta a”.

O ni lẹyin ti ẹni ti wọn ja lole fẹjọ sun tan ni ọwọ awọn tẹ Maikudi ati gbogbo maaluu ti wọn ji gbe.

O fi kun un pe iwadii ṣi n lọ, bẹẹ ni akitiyan n lọ lati mu awọn afurasi meji yooku.

Leave a Reply