O ma ṣe o, ọmọkunrin yii lọọ wẹ lodo, lomi ba gbe e lọ

Monisọla Saka

Ọkunrin ẹya Igede, lati ipinlẹ Benue, Sunday Ogah, ti ṣe bẹẹ bomi lọ lasiko to lọọ luwẹẹ, to si ri sinu odo Eyinwa, to wa nijọba ibilẹ Odogbolu, nipinlẹ Ogun.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, niṣẹlẹ to da gbogbo agbegbe naa si ibanujẹ nla waye.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, Otusanya Abayọmi, ti i ṣe ọmọ ilu naa ni Ogah tẹle wa siluu ọhun to fi lọọ gbafẹ nibi odo to gbe e lọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ ninu atẹjade to fi sita bayii pe, “Ọjọ buruku eṣu gbomi mu lọjọ naa jẹ fawọn eeyan ilu Eyinwa, to wa nijọba ibilẹ Odogbolu, nipinlẹ Ogun, nigba ti Ọgbẹni Otusanya Abayọmi, to n gbe ni Igbe-laara, Ikorodu, nipinlẹ Eko, gba teṣan ọlọpaa Odogbolu lọ, pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni oun ati ọrẹ oun kan to n jẹ Sunday Ogah, to jẹ ẹya Igede lati ipinlẹ Benue, jọ wa si ilu awọn.

“O ni ọrẹ oun ko sọ foun atawọn ti awọn jọ jokoo pọ to fi gba odo lọ. Nigba to ya ni iroyin kan de ọdọ oun pe ẹni ti wọn n pe ni Sunday Ogah yii ti lọọ luwẹẹ ni odo Eyinwa, o si ti ri wọ isalẹ omi lọ.

Ni kete ti ọrọ yii to awọn agbofinro leti ni ọga ọlọpaa teṣan Odogbolu ti ko awọn ọlọpaa ati awọn omuwẹ agbegbe naa jọ lati wa oku ọkunrin naa jade ninu omi, ṣugbọn ti gbogbo akitiyan wọn ko ti i so eeso rere”.

Odutọla tẹsiwaju pe gbogbo akitiyan lati wa oku ọkunrin naa jade lawọn n ṣe, ki wọn le tete ribi fi to awọn ẹbi oloogbe leti.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Abiọdun Alamutu, to kilọ fawọn ọmọde ati ọdọ lati yago fun wiwẹ ninu omi ti wọn ko ba mọ bo ṣe jin to, ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ẹbi ọkunrin oloogbe, bẹẹ lo ṣe e laduura pe Ọlọrun yoo rọ wọn lọkan.

Leave a Reply