O ga o! Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun gun ẹgbẹ ẹ pa

Monisọla Saka

Abubakar Isa, ọkunrin ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan ti fibinu fufu rẹ sọ idile ọga ọlọpaa kan to ti fẹyinti sinu ipayinkeke, gẹgẹ bo ṣe gun ọmọ wọn, Adamu Isa, lọbẹ pa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti ariyanjiyan nla kan bẹ silẹ laarin awọn ọrẹ mejeeji yii, ni Abubakar ba fibinu fa ọbẹ yọ, to si ti i bọ Adamu lọrun lẹyinkule ileeṣẹ NEPA, to wa nijọba ibilẹ Ningi, ipinlẹ Bauchi, tawọn mejeeji n gbe.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, nibi ọrun, to sun mọ ọna ọfun gangan, ni Abubakar ti gun ọmọdekunrin yii lọbẹ, wọn ko si ri i gbe dele iwosan to fi dagbere faye.

Gẹgẹ bi SP Ahmed Wakil, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, ṣe sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, o ni lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, teṣan ọlọpaa Ningi, to wa nijọba ibilẹ naa ni wọn ti gba ipe pajawiri latọdọ ọga ọlọpaa to ti fẹyinti, DSP Kasuwa Isa.

Ọlọpaa to n gbe lẹyin ọfiisi INEC yii ṣalaye pe Abubakar Isa, ẹni ọdun mẹẹẹdogun, lo fi ọbẹ gun ọmọ oun, Adamu Isa, ẹni ọdun mẹẹẹdogun lọbẹ lẹyinkule ileeṣẹ mọnamọna (NEPA), to wa ni Ningi.

“Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ kọja iṣẹju kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni DSP Kasuwa, pe awọn agbofinro pe ọrẹ ọmọ oun ti gun un lọbẹ. Ni kete ti wọn gba ipe yii ni awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati teṣan ọlọpaa Ningi ti gba ibẹ lọ, ṣugbọn oku ọmọkunrin ọhun ni wọn ba, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu ijọba, General Hospital, Ningi, nibi tawọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe o ti dakẹ”.

Wakil tẹsiwaju pe ọwọ ti tẹ afurasi, o si ti wa lakata awọn, bẹẹ ni iwadii ti n lọ lori ọrọ naa.

Leave a Reply