Nitori foonu, Yakubu pa Sikiru, lo ba lọọ ju oku ẹ si ṣalanga

Faith Adebọla

Ọwọ awọn agbofinro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, ti tẹ afurasi ọdaran ọmọọdun mọkandinlogun kan, Yakubu Tanko, ti wọn fẹsun kan pe niṣe lo pa ọrẹ rẹ, Sikiru Tajudeen, nigba ti wọn jọ n ṣe fa-n-fa lori ọrọ foonu alagbeeka kan, lẹyin to si ri i pe ọkunrin naa ti dakẹ, lo ba palẹ oku rẹ mọ lai fu ẹnikẹni lara, o si lọọ ju u sinu ṣalanga kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Wasiu Abiọdun, to sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta yii, lasiko ti wọn n ṣafihan afurasi naa, o ni:

“Ni ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni nnkan bii aago meje alẹ, ọwọ awọn ọlọpaa ẹka ilu Bosso, tẹ Yakubu Tanko, ẹni ọdun mọkandinlogun, to n gbe laduugbo Tundun-Filani, niluu Minna, latari bo ṣe ṣeku pa Sikiru Tajudeed, ọmọọdun mẹrinla, ti wọn jọ n gbe adugbo kan naa.

“Lọjọ yii kan naa lawọn mọlẹbi oloogbe yii ti waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa pe lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, iyẹn ọjọ to ṣaaju, lawọn ti wa ẹni awọn ti, wọn ni ni nnkan bii aago mẹsan-aabọ alẹ patapata lawọn ti ri i kẹyin nile, ati pe nigba ti wọn ṣayẹwo si yara rẹ lọjọ keji, wọn ri ṣokoto ileewe rẹ, olugbondoro kan, okuta, ati ipa ẹjẹ to ta kaakiri.

Ṣaaju asiko ti wọn fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran yii lawọn eeyan adugbo tiṣẹlẹ yii ti waye mu ẹsun wa pe awọn ṣakiyesi oorun buruku kan to n bu jade ninu ṣalanga kan nibẹ, wọn lo jọ pe ẹran kan lo ku, oorun naa si n bu tii.

Nigba tawọn ọlọpaa ṣi ṣalanga ọhun, wọn ri apo idọhọ ti wọn so lẹnu pa, nigba ti wọn si fi okun fa apo idọhọ ọhun jade, ti wọn tu u, oku Sikiru ni wọn ri nibẹ to ti wu bente. Eyi lo mu ki wọn tubọ fimu finlẹ, tọwọ si ba Yakubu.

Lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, Yakubu ti jẹwọ pe ni tododo, oun loun pa ọrẹ oun yii, o ni igi kan loun mu nile idana wọn nigba toun ba a loju oorun to n sun, oun si fọ igi naa mọ ọn lori, oju oorun lo gba de oju iku.

Wọn tun bi i leere ohun to fa a to fi ṣe bẹẹ, o ni oun naa ko le sọ pato ju pe ẹmi eṣu lo ba le oun, o ni oloogbe naa fun oun ni foonu rẹ kan lati ba oun ṣaaji rẹ, foonu yii si joju-ni-gbese, lero buruku ba wa sọkan oun pe k’oun kuku pa a lati jogun foonu rẹ.

Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.

Leave a Reply