Asẹyin ilu Isẹyin da si ija Wasiu Ayinde ati onilu rẹ tẹlẹ, Ayanlọwọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi onilu Wasiu Ayinde tẹlẹ, Ọgbẹni Ayankunle Ayanlọwọ, ṣe jẹ ọmọ agbegbe Isẹyin, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ  Ọyọ, Asẹyin tilu Isẹyin, Ọba Sẹfiu Ọlawale Oyebọla Ajirọtutu Adeyẹri (Kẹta), ti da si ija to wa laarin gbajugbaja olorin Fuji naa pẹlu onilu rẹ atijọ yii.

Lọjọ Aje, Mọnde , ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, l’Ọgbẹni Ayanlọwọ, ṣabẹwo si Ọba Adeyẹri, ninu eyi to ti ṣalaye bi Wasiu Ayinde ti awọn eeyan tun mọ si K1 ṣe fiya jẹ ẹ titi to fi kuro lẹyin ọkunrin naa nigba ti iya taa wi yii papọju.

Gẹgẹ bo ti ṣe sọ ọ lọpọ igba kaakiri ori ẹrọ ayelujara ṣaaju, ọkunrin onilu yii royin bo ṣe jẹ pe nigbakuugba ti wọn ba pe awọn sode ariya gẹgẹ bii ẹgbẹ akọrin, owo nla nla lawọn maa n pa loju agbo, ṣugbọn owo ti ko too jẹun lasan lọba awọn onifuji naa maa n fun oun atawọn ọmọ ẹyin ẹ yooku.

Pabanbari ibẹ ni bo ṣe ni K1 n ba iyawo oun laṣepọ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹsun wọnyi l’Alhaji Ayinde, to tun jẹ Olori Ọmọọba Akilẹ ilẹ Ijẹbu, ti ta ko ṣaaju, to ni irọ pata lọkunrin onilu naa fi wọn pa.

Ṣugbọn niwọn igba to ti jẹ pe Wasiu Ayinde funra rẹ ki i ṣe àjèjì niluu Isẹyin, to jẹ pe ọmọ ilu naa lọkan ninu awọn iyawo to fẹ sile, to si jẹ pe ọmọ ilu Ado-Awaye, lẹgbẹẹ Isẹyin, ni Ayanlọwọ, Asẹyin tilu Isẹyin ti gba lati ba wọn pari ija naa.

Nigba to n ṣe ipinnu yii lasiko abẹwo ọhun, Ọba Adeyẹri paṣẹ fun Ayanlọwọ lati yee maa rojọ ọga ẹ tẹlẹ naa fawọn oniroyin ati nibikíbi lori ẹrọ ayelujara mọ. Bẹẹ lo rọ awọn mejeeji lati sinmi ija, ki wọn si gba alaafia laaye.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo ti gbọ ọrọ yii lori ẹrọ ayelujara kaakiri, mo si gbọ oriṣiiriṣii ọrọ ti awọn eeyan n sọ naa, ṣugbọn emi gẹgẹ bii ọba, mi o ni i ro ile apa kan da apa kan si, ohun to maa fopin si ija yii ni mo fẹ. Nitori naa, mo rọ ẹyin mejeeji lati gba alaafia laaye, kẹ ẹ jẹ ka pari ẹ nitubi inubi”.

Ni kete to kuro laafin Asẹyin, l’Ọgbeni Ayanlọwọ ti ṣeleri fawọn oniroyjn pe oun ko jẹ tun pariwo ọga oun tẹlẹ naa fun gbogbo aye mọ, ati pe oun yoo faaye gba ipade alaafia laarin oun pẹlu Oluaye ni ibamu pẹlu aṣẹ ọba alade naa.

Leave a Reply