Gbogbo awọn oloṣelu ti wọn n ko palietiifu pamọ n fa egun sori ara wọn ni – Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti kilọ fun gbogbo awọn oloṣelu ti wọn n raga bo ounjẹ palietiifu tijọba ko fun wọn lati fun awọn araalu kaakiri orileede yii lati ṣọra fun ibinu Ọlọrun.

Ọba Akanbi ṣalaye pe egun ni ki ẹnikẹni maa ko ounjẹ to yẹ fun awọn araalu pamọ lai bikita ipenija ọrọ-aje ti awọn eeyan n dojukọ.

Lasiko ti Oluwoo n pin ounjẹ kaakiri agboole niluu Iwo gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe lọdọọdun lo ṣalaye pe adari tootọ gbọdọ ni imọlara ohun ti awọn eeyan rẹ ba n la kọja, ko si wa ọna abayọ lati tu wọn lara.

O ni ọkẹ aimọye owo loun na lori eto naa lọdun yii, ṣugbọn o jẹ idunnu oun pe oun dẹrin-in pẹẹkẹ awọn eeyan ilu Iwo ti Ọlọrun fi oun ṣe ọba le lori.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Ohun ti ko bojumu ni ki oloṣelu maa ko awọn ounjẹ palietiifu to tọ si awọn araalu pamọ. Melo lo fẹẹ jẹ nibẹ? Egun ni iru ẹni bẹẹ n fa sori ara rẹ’’

Ọba Akanbi lo asiko naa lati ke si ijọba apapọ pe dipo ki wọn maa ko nnkan palietiifu fun awọn jẹgudujẹra oloṣelu, ijọba le maa lo awọn ori-ade lati pin palietiifu yii.

O ni awọn kabiesi ni wọn sun mọ awọn araalu wọn ju, wọn si lanfaani lati wọnu agboole lọọ ba wọn gẹgẹ bi oun ṣe maa n ṣe, nitori naa, yoo rọrun fun wọn lati pin palietiifu yii.

Oluwoo parọwa si awọn ọmọ orileede Naijiria lati ni suuru fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, o ni ọlọpọlọ pipe, to si ni afojusun rere fun orileede yii ni.

Ọkan lara awọn ti wọn janfaani eto naa, Alhaji Oyewale, dupẹ lọwọ Ọba Akanbi, o ni ko si ọba to ṣe iru rẹ ri ninu itan ilu Iwo, o si gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun un.

 

Leave a Reply