Awọn agbebọn ya bo ileewe ijọba ni Niger, wọn pa ọmọleewe kan, wọn si ji tiṣa atawọn to ku gbe

Faith Adebọla

 

 

 

Awọn janduku agbebọn ti ṣakọlu si ileewe ijọba, Government Science College, to wa ni lagbegbe Kagara, nijọba ibilẹ Rafi, nipinlẹ Niger, wọn yinbọn pa ọmọleewe kan, wọn si ji awọn ọmọleewe to ku atawọn tiṣa wọn gbe sa lọ.

Oru mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni wọn ni iṣẹlẹ ibanujẹ naa waye, wọn ni nnkan bii aago meji ọganjọ oru tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, lo ṣẹlẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn niru aṣọ ileewe (yunifọọmu) tawọn akẹkọọ naa n wọ lawọn agbebọn naa wọ, eyi si ni ko jẹ kawọn eeyan to ṣee ṣe ko ri wọn fura pe iwa laabi kan ni wọn fẹẹ lọọ hu.

Benjamin Doma ni wọn porukọ majeṣin ọmọleewe ti wọn da ẹmi ẹ legbodo ọhun, wọn si fipa ja geeti ọgba tawọn olukọ ileewe naa n gbe pẹlu awọn mọlẹbi wọn, wọn ko gbogbo wọn wọ’gbo lọ.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) to jẹ ka gbọ nipa iṣẹlẹ yii sọ pe titi di bayii, ko ti i ṣee ṣe lati sọ pato iye eeyan ti wọn ji gbe, ati iye ọmọleewe tọrọ naa kan.

Sẹnetọ tẹlẹ kan lati apa Oke-Ọya, Sẹnetọ Shehu Sanni fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O sọ lori atẹ ayelujara (tuita) rẹ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, o loun ṣẹṣẹ ba ọga agba (Principal) ileewe naa sọrọ lori aago tan ni, o lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ foun. Sanni ni ọkan lara ileewe toun lọ nigba toun wa lọmọde nileewe ọhun.

Awọn agbofinro ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii, lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply