Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Igbiyanju lati ri dokita ati nọọsi tawọn agbebọn kan ji gbe l’Ọjọruu to kọja yii, lọna Abẹokuta si Imẹkọ, ko seso rere rara, nitori meji ninu awọn ọlọdẹ to n wa wọn tun bọ sọwọ awọn agbebọn naa ni, ti wọn yinbọn mọ wọn.
Ọsẹ to kọja yii ni ikọlu eyi tun waye, yatọ si bi wọn ṣe yinbọn lu awọn ọlọdẹ yii, niṣe lawọn agbebọn naa tun dana sun ọkada mẹsan-an ati mọto meji tawọn ọlọdẹ naa fi n wọgbo kiri.
Ibi kan ti wọn n pe ni Ọdẹtẹdo-Idi-Iroko, n’Imẹkọ, ni wọn ti kọ lu awọn ọlọde ibilẹ naa.
Awọn ọlọdẹ mẹrindinlọgbọn (26) lo wọgbo naa ti wọn n wa Dokita Ọladunni Ọdẹtọla ati Nọọsi Bamgboṣe. Lati Ọjọruu to kọja ti wọn ti ji wọn gbe ninu ọkọ Camry ti wọn wa lawọn ọlọdẹ atawọn fijilante ti n gbiyanju lati ri wọn gba pada. Eyi naa lo si fa a ti wọn fi to mẹrindinlọgbọn ninu igbo ti wọn ti waa kọ lu wọn yii.
Ibọn AK47 la gbọ pe awọn agbebọn to kọ lu awọn olọdẹ yii lo, ko si pẹ wọn ti wọn fi ṣina ibọn bolẹ, ti wọn tun dana sun mọto atawọn ọkada awọn ọlọdẹ.
ALAROYE gbọ pe ogun miliọnu naira lawọn agbebọn yii n beere lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe naa, wọn ni awọn ko ni i fi wọn silẹ bowo ọhun ko ba pe.