Awọn agbebọn yinbọn mọ oni POS lẹyin ti wọn gbowo ati foonu rẹ l”Ado-Ekiti 

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Ipaya ati aibalẹ ọkan, eyi to mu ki awọn eeyan maa sa kijokijo lo bẹ silẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin yii, lagbegbe Adebayo, niluu Ado-Ekiti, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ekiti, nigba ti awọn ọdọ langba mẹta kan sadeede yibọn mọ ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji kan to n ṣowo POS ni agbegbe naa.

Ni deede aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Aje, ni iṣẹlẹ to ba gbogbo awọn ti wọn wa ni agbegbe naa lẹru yii waye. ALAROYE gbọ pe ni kete ti ọkunrin yii de si ibusọ POS rẹ lọjọ naa lati bẹrẹ iṣẹ oojọ rẹ ni

awọn janduku mẹta naa bọ silẹ lori ọkada, ti meji lara wọn mu ibọn lọwọ, ti ẹni kan yooku si wa lori ọkada, to n wo ọna fun awọn ẹgbẹ rẹ fẹẹ ja oni POS lole.

Bi wọn ṣe de ibusọ okunrin oniṣowo POS yii ni wọn yọ ibọn ti i. Lẹyin ti wọn gba owo to pọ lọwọ rẹ tan ni wọn tun gba ẹrọ ilewọ rẹ. Bayii ni wọn bẹrẹ si i yinbọn si ọmọkunrin naa lẹsẹ titi to fi ṣubu, ti ko si le dide nilẹ mọ.

Niṣe ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke ni kete ti wọn pada sori ọkada ti wọn gbe wa si agbegbe naa. ALAROYE gbọ pe  ọlokada to gbe wọn wa sibi iṣẹlẹ naa ko pana ọkada titi ti wọn fi ṣe ọsẹ naa tan.

Nise ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke nigba ti wọn fẹẹ maa sa lọ, eyi to da ijaya silẹ ni agbegbe naa, ti gbogbo awọn ọlọja ati awọn to n kọja ni adugbo yii si bẹrẹ si i sa kijokijo, pẹlu iro ibọn to n dun lakọlakọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn janduku agbebọn naa ti ẹnikan ko ti i mọ gba owo to pọ lọwọ okunrin naa.
Nigba to n sọ iriri rẹ fun ALAROYE, okunrun oni POS naa to wa nileewosan aladaani kan niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n gba itọju lọwọ sọ pe ni kete ti oun de si isọ oun lọjọ naa loun deede ri awọn ọdọ mẹta kan pẹlu ọkada ti wọn gbe wa si agbegbe naa.

O loun beere lọwọ wọn boya wọn fẹẹ gbowo ni, ṣugbọn lọgan ni ọkan lara wọn fa ibọn yọ, to si kọju rẹ si oun. Ọmọkunrin naa ni oun kọkọ kọ lati jọwọ ẹrọ ilewọ oun fun wọn lẹyin ti wọn ti gba obitibiti owo lọwọ oun, ṣugbọn niṣe ni wọn da ibọn bo oun lẹsẹ, lẹyin eyi ni wọn fi agbara gba ẹrọ ilewọ naa lọwọ oun. O fi kun un pe mẹta lawọn janduku naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ọga ọlọpaa kan ni olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, logan ni awọn si bẹrẹ iwadii lati le ri awọn ọdaran naa mu.

 

O rọ awọn araalu pe ti wọn ba kẹẹfin awọn ajoji l’aduugbo wọn, ki wọn tete fi to awọn ọlọpa leti.

Leave a Reply