Adewale Adeoye
Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ lọrọ iku igbakeji Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Oloogbe D.C.P Gbolahan Oyedemi, to pokunso sinu ilẹ rẹ niluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin–in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ṣi n ya gbogbo eeyan lenu gidigidi pe ki lo Le Mu ọkunrin naa pa ara ẹ.
ALAROYE gbọ pe olude Ajinde ni ọkunrin naa lọọ ṣe ni ilú abinibi rẹ l’Ogbomọṣọ.
Wọn ni bi okunrin ti wọn ni ko niyawo, òun nìkan lo n da gbe yii ṣe delẹ lo ni ki onikaluku awọn ẹṣọ to n sọ ọ maa lọ sile, ki onikaluku lọọ ṣọdun nile wọn.
Leyin tawọn ọmọọṣẹ rẹ lọ tan ni wọn ni ọkunrin to ti figba kan jẹ ẹṣọ (ADC) fun gomina ipinle Ọyọ tẹlẹ, Oloogbe Christopher Adebayọ Alao Akala nigba aye rẹ pojobo okun, to sí so ara rẹ, nibi ti ọlọjọ de ba a.
Agbọ-sọgba-nu ni iku igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa Eko ọhun si gbogbo awọn to gbọ ọ.
Iwadii akoroyin wa fi han pe Oyedemi ati iya rẹ ni wọn jọ n gbe ile to kọkọ kọ fún iya rẹ, eyi to wa ni agbègbè Randa, niluu Ogbomoso, ko too ṣẹṣẹ kọ omi-in, nibi ti òun nìkan n gbe, to sí pada pokunso si bayii.
Ọkan lara awọn ọrẹ oloogbe naa toun ati ẹ jọọ ṣiṣẹ papọ lọdọ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ sọ pe:
‘Ile nla kan bayii to kọ fun iya rẹ loun ati mama rẹ jọ n gbe tẹlẹ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Randa, niluu Ogbomọṣọ, ṣugbọn loju-ẹsẹ to pari ile tuntun mi–in to kọ funra lo ko lọ sile ọhun to wa lagbegbe Petros Academy, ni Federal Low-cost. Inu ile ọhun lawọn araadugbo naa ti ba oku rẹ laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Ọga olopaa kan to ba akoroyin Daily Trust sọrọ sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii, ati pe gbogbo awọn omoose rẹ, to fi mọ awọn to ri i gbeyin ko too pokunso ni wọn máa f’oro wa l’enu wo