Aye le o: Wọn di oku ọmọkunrin kan sinu apo, wọn si gbe e sidii ọgẹdẹ n’Iyin-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Kayeefi nla lo jẹ fun gbogbo eeyan ilu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irepọdun/Ifẹlodun, nipinlẹ Ekiti, pẹlu bi wọn ṣe ṣadeede ba oku ọmọdekunrin kan ti wọn ko ti i mọ ibi to ti wa ti wọn di sinu  apo nla kan, ti wọn si gbe apo naa si idi ọgẹdẹ, ni adugbo kan ti wọn n pe ni Ararọmi niluu naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Gẹgẹ bi awọn araalu naa tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni awọn kan deede ri apo nla naa ti wọn fi okun di lẹnu, to si ti to bii ọjọ mẹta ti wọn ti gbe e sidii ọgẹdẹ ọhun, ṣugbọn ko tiẹ sẹni to ja a kunra lati wo ohun to wa ninu rẹ.

Ṣugbọn nigba ti oorun buruku bo gbogbo adugbo naa kan, ti awọn araadugbo naa ko si gbadun mọ ni wọn ba wo o pe kawọn wo ohun to wa ninu apo ti wọn ko mọ ẹni to gbe e sidii ọgẹdẹ ọhun, nitori niṣe ni eṣinṣin n kun ọọkan ibẹ, to si tun jẹ pe agbegbe naa ni oorun ọhun ti n bu tii wa.

Nigba ti wọn sun mọ apo naa ti wọn ri i pe ibẹ ni oorun naa ti n jade, awọn araadugbo naa ko fọwọ kan apo ọhun, ile ọba ni wọn gba lọ. Wọn lọọ fọrọ naa to Ọba Adeọla Adeniyi Ajakaye leti. Oju-ẹsẹ ni ori-ade naa ti lọọ fọrọ ọhun to awọn agbofinro leti.

Bakan naa ni Kabiyesi yii tun lọ fi iṣẹlẹ yii to awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ Onitẹsiwaju to wa niluu naa leti. Awọn ọlọpaa pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa ni wọn sun mọ abami apo naa, ti wọn si tu u.

Iyalẹnu lo jẹ pe oku gende-kunrin kan ni wọn ba ninu apo naa, bi wọn si ti tu u ni oorun tubọ bo’lẹ, nitori oku naa ti jẹra, o si ti to bii ọjọ mẹrin to ti wa nibẹ.

Awọn eeyan adugbo yii to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ṣalaye pe o ti to bii ọjọ mẹta ti wọn ti ṣakiyesi apo naa ti wọn fi okun di i lẹnu, ti wọn ti ja a sidii ọgẹdẹ kan to wa ni adugbo naa. Awọn miiran ṣalaye fun akọroyin ALAROYE pe awọn gburoo ọkọ kan to kọja ni nnkan bii aago meji oru ọjọ ti ja oku yii sidii ọgẹdẹ naa, ati pe ọkọ naa ko lo ju iṣẹju marun-un lọ to fi ṣẹri pada. Awọn ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ ìjọba ibilẹ yii ni wọn gbe oku ọhun lọ si ile igbokuu-pamọ-si to jẹ tijọba, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ileewosan yii ko gba a lọwọ wọn nitori ipo to wa ki wọn too gbe e debẹ. Awọn araalu ni wọn pada pese ilẹ nibi ti wọn maa n sin oku ajeji si, ti wọn si sin in sibẹ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa ilu Iyin-Ekiti ti fi lẹta iṣẹlẹ naa ranṣẹ si olu ileeṣẹ awọn to wa ni Ado-Ekiti. O fi kun un pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply