Ṣeun Kuti ju bọmbu ọrọ: Bo ba jẹ ọmọ olowo lẹ fun loyun, ṣe ẹ maa sọ pe ẹ fẹẹ ṣe ayẹwo ẹjẹ (DNA)

Monisọla Saka

Olorin taka-sufee ilẹ wa to jẹ ọmọ bibi inu Fẹla Anikulapo Kuti, ti i ṣe agba onkọrin to ti doloogbe nni, Ṣeun Kuti, ti sọ ero rẹ lori ayẹwo ẹjẹ ti yoo fidi ọkunrin to lọmọ mulẹ, eyi ti wọn n pe ni DNA.

Bo tilẹ jẹ pe Ṣeun ko darukọ ẹnikẹni tabi idile kankan to fi n sọrọ, o ni ọwọ agbara tawọn ọkunrin n lo lori obinrin ni, nitori wọn ko le dan an wo pẹlu ọmọ ọlọla.

Ṣeun ṣalaye pe, “Ni temi o, mo lero pe ṣiṣe DNA fun ọmọ, ti n ba maa ṣe DNA gan-an, ki i ṣe nitori ọmọ yẹn gangan. Ọkunrin yoowu tabi ẹnikẹni to ba tọ ọmọ tabi eeyan titi di bii ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun, koda bo jẹ ọdun mẹta si mẹrin, ọmọ ti eeyan ti tọ ti ifẹ ti jọ wa laarin yin, ki ayẹwo kan waa sọ pe iwọ kọ lo bi i, ṣe wa a waa sọ pe o o nifẹẹ ọmọ yẹn mọ ni?

A jẹ pe ifẹ irọ ni, a jẹ pe o o nifẹẹ ọmọ yẹn latilẹ wa ni.

“Ṣe awọn eeyan kan kọ ni wọn n tọ ọmọ alainiyaa ati baba ni? Awọn kan kọ ni wọn n gba ọmọ tọ bii tiwọn ni, ti wọn n tọ wọn, ti wọn si n nifẹẹ wọn bii pe awọn ni wọn bi wọn? Ṣe awọn eeyan ki i ṣe e ni? Ohun ti wọn n ṣe daadaa ni. Ailoye wa nipa aye lo fa a tawọn eeyan fi n ro pe ki gbogbo nnkan jẹ ti tawọn nikan.

“Ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ wa lori boya eeyan fọkan tan ọkọ tabi iyawo rẹ. Pe eeyan n ṣe DNA, itumọ rẹ ni pe o ko fọkan tan ololufẹ rẹ. Ko si nnkan ire tabi ohun to buru kan nibẹ. Ọrọ ifọkantan ni, ere lasan lawọn eeyan si fi n ṣe tawọn yii fi n gba a si nnkan mi-in. Ki lo de ti gbogbo yin waa sọ ọ di babara?

“Ko sohun tẹ ẹ fẹẹ sọ tabi fidi ẹ mulẹ lati sọ pe DNA ṣiṣe ko ni i ṣe pẹlu fifi ọkan tan ara ẹni. Ọrọ ainifọkantan ninu ara ẹni ni ṣiṣe DNA, ko sohun tẹ ẹ fẹẹ sọ fun mi lori iyẹn.

“Ti ọkan ninu yin ba fun ọmọ baba olowo, bilọnia loyun, tabi ki iru ọmọ bẹẹ sọ pe ẹyin lẹ ni oyun inu oun, wọn o bi ẹ daa ko o sọ pe o fẹẹ ṣe DNA. Ṣe wọn bi ẹ daa pe ọmọ biliọnia kan wo apa ibi ti o wa, o waa kọ oyun si i lọrun pe iwọ kọ lo ni in? Ṣe o maa beere fun DNA? Mo beere ni. Ki lohun ti a n sọ nibi gan? Ki iru ọmọ eeyan bii Bill Gates sọ pe o fun oun loyun nisinyii, ọmọ di tiẹ niyẹn! Abi ọmọ eeyan bii Elon Musk, o di tiẹ niyẹn.

“Ki wọn waa bi ọmọ tan ki gbogbo ara ẹ funfun titi de irun ori, ko tun waa ni ẹyinju buluu, ṣe wa a laya lati kọ ọ tabi beere DNA?

Nigba to o ba ri ọmọ yẹn pẹlu bo ṣe funfun gboo to, ariwo, ‘ọmọ mi ree, emi ni mo ni ọmọ yii’ ni wa a maa pa. Wa a maa ni ẹnikẹni to ba loun fẹẹ gba ọmọ yii lọwọ rẹ n wa ọran ni”.

Bayii ni Ṣeun sọ ọrọ rẹ. Nigba tawọn kan fara mọ ero rẹ pe koda, bi ọmọ naa ki i ṣe tawọn, awọn ko le tori ẹ koriira rẹ, awọn mi-in ni apo ara ẹ lo sọ gbogbo iyẹn si.

Wọn ni ti ayẹwo ẹjẹ ba lọọ sọ pe oun kọ loun ni gbogbo awọn ọmọ toun n tọju lọwọ bayii, toun n pe ni toun, iru obinrin bẹẹ yoo sunkun kikoro.

Bẹẹ lawọn mi-in ni oju wo lawọn fẹ fi maa wo ọmọ to jẹ ere agbere iyawo tabi ọkọ awọn lakata awọn.

Wọn ni esi ayẹwo DNA ko tilẹ mọ lori agbere tabi fifi ọbẹ ẹyin jẹ ara ẹni niṣu nikan, wọn ni awọn ko mọ boya o ti gbọ nipa aṣigbe ọmọ lọsibitu ri. Ati pe aimọye ọrọ lo ti ṣẹlẹ ri ti wọn lawọn kan n paarọ ọmọ nile iwosan.

Leave a Reply