Ọwọ ti tẹ ẹ o: Lẹyin bii ọdun meji ti wọn ti n wa a, ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Bọde Ọlakayọde, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Bọde Ìtaàpá.

Lati oṣu Keje, ọdun 2022, ni wọn ti kede pe awọn n wa ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ọhun fun oniruuru ẹsun to ni i ṣe pẹlu ipaniyan, jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, gbigbimọ-pọ huwa buburu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lọdun naa lọhun-un, ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, gbe atẹjade kan jade, nibi to ti sọ pe Bọde ti sọ ara rẹ di ẹrujẹjẹ siluu Ileṣa, o si n da wahala silẹ laarin ilu.

Wọn ni ẹbun nla wa fun ẹnikẹni to ba le tu aṣiri ibi to wa, bẹẹ si ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi ọwọ ọdaran mu ẹnikẹni to ba gbe e pamọ sinu ile. Latigba naa ni wọn si ti n dọdẹ rẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ko too di pe ọwọ ba a bayii.

ALAROYE gbọ pe abule kan ti wọn n pe ni Orógójì, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakunmọsa, nipinlẹ Ọṣun, ni ọwọ ti tẹ ẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu to kọja yii. A gbọ pe awọn ikọ ọlọpaa to n gbogun ti awọn ajinigbe, iyẹn ‘Ọṣun State Anti-Kidnapping Squad’, ni wọn lepa rẹ de abule naa, ti wọn si wa a jade nibi to sa pamọ si.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Ọpalọla ṣalaye pe loootọ ni ọwọ ti tẹ Bọde, ṣugbọn oun ko le sọ pupọ lori rẹ lasiko yii, nitori iwadii ṣi n tẹsiwaju.

Leave a Reply