Ẹfun abeedi! Lasiko ti ọlọpaa yii ati ọrẹbinrin rẹ n muti lọwọ lo gun un pa toyun-toyun

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede South Africa, ti tẹ ọkan lara wọn to gun ọrẹbinrin ẹ ti i ṣe agbofinro bii tiẹ pa pẹlu oyun ninu.

Niluu Durban, lorilẹ-ede South Africa, niṣẹlẹ naa ti waye laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii. ALAROYE gbọ pe ninu ile rẹ to wa ni agbegbe Joseph Nduli Street, ni ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yii ti ṣeku pa obinrin naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i sọ ohun to mu un hu iru iwa naa, ọti ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ololufẹ mejeeji n mu lọwọ ti ẹmi eṣu fi wọ’nu ọkunrin yii, to si gun ololufẹ ẹ pa pẹlu oyun ninu rẹ.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni wọn ti ni, “Ohun ti a gbọ ni pe awọn ololufẹ mejeeji yii jọ n mu ọti lọwọ ni afurasi fi gun obinrin naa pa.

A tun gbọ pe ọkunrin yii ya fọto ati fidio bi obinrin naa ṣe n japoro ko too gbẹmii mi. O fi awọn fọto ati fidio yii ṣọwọ sawọn eeyan kan, lẹyin naa lo ju u sori ayelujara. O ṣee ṣe ko jẹ ọti amupara ati ilokulo oogun oloro mi-in lo ṣokunfa iwa ọdaju ti ọkunrin yii hu, ṣugbọn a ko ti i le sọ”.

Wọn ni niwọn igba ti ọwọ ti tẹ ẹ, lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni yoo ti maa yọju sile-ẹjọ lati wi tẹnu ẹ.

Leave a Reply