Ab’ẹẹri Sanusi, suuti lo fi tan ọmọkunrin to larun ọpọlọ to fi fipa ba a lo pọ

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti tẹ Sanusi Umar, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), to n ta ìgbá, nitori bo ṣe fipa ba ọkunrin bii tiẹ, ọmọọdun mẹwaa to ni ipenija ọpọlọ lajọṣepọ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni SP Ahmed Wakil, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin. Wakil ni suuti ọgbọn Naira (#30), ti Sanusi ra f’ọmọ naa lo fi tan an wọ kọrọ, to si lọọ ba a dan palapala ọhun wo.

O ni, “Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn ikọ agbofinro Operation Restore Peace, nipinlẹ Bauchi, fi panpẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan.

“Suuti ọgbọn Naira, ni afurasi yii fi tan ọmọdekunrin naa pe ko tẹle oun lọ si agbegbe kan to maa n da paroparo ni ẹyin ile-epo AIB, to wa loju ọna Kofar Ran, nibẹ lo ti fipa ba a lo pọ ni ọkunrin si ọkunrin”.

Wakil ni nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ, wọn ti gbe ọmọdekunrin ti wọn ko darukọ rẹ yii lọ sileewosan ẹkọṣẹ Iṣẹgun Fasiti ilu Bauchi, Abubakar Tafawa Balewa University Teaching Hospital, nibi ti wọn ti n ṣe oniruuru ayẹwo fun un lati mọ boya o wa ni ilera pipe.

O fi kun un pe ni kete ti wọn ba ti pari iwadii lawọn yoo foju afurasi bale-ẹjọ.

Leave a Reply