O ṣẹlẹ, Yọmi Fabiyi kọ lẹta siyawo Mohbad, eyi lohun to wa nibẹ

Monisọla Saka

Oṣerekunrin ilẹ wa nni, Yọmi Fabiyi, ti kọwe si Ọmọwumi Alọba, ti i ṣe iyawo gbajumọ olorin taka-sufee to ṣalaisi nni, Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad.

Ninu lẹta ti ọkunrin ti awuyewuye ki i sin lori rẹ kọ si Wumi yii lo ti sọ awọn idi ti mọlẹbi ọkọ rẹ fi lẹtọọ lati sọ fun un pe ko ṣe ayẹwo ẹjẹ ti yoo fidi rẹ mulẹ pe ọmọ wọn lo bi Liam, to da oun ati Mohbad pọ.

Loju opo Instagraamu rẹ ni Yọmi kọ ọ si lẹsẹẹsẹ, awọn idi ti Wumi ṣe gbọdọ ṣe ayẹwo naa lai fi falẹ.

O ni, “Mo ba ọ daro ninu ibanujẹ to ṣẹ sinu ẹbi yin lori iku Mohbad. Ọlọrun yoo fori ẹṣẹ rẹ jin in. Mo n kọwe yii si ọ lori ariyanjiyan to wa nilẹ nipa ayẹwo ẹjẹ lati mọ baba ọmọ to kan Liam to o bi fun Mohbad, ati iwadii iru iku to pa a to n lọ lọwọ.

“Awọn koko ti mo fẹẹ to kalẹ yii lo fa a tawọn ẹbi Mohbad fi le pa ẹ laṣẹ lati ṣe ayẹwo ẹjẹ DNA.

Akọkọ ni pe, ta a ba wo bi nnkan ti ṣe n lọ, iku Mohbad ki i ṣe oju lasan, bii ẹni pe wọn pa a ni, agaga pẹlu nnkan to ṣẹlẹ ni bii wakati mejidinlaaadọta ki ẹmi rẹ too bọ. Awọn igbimọ to n wadii iku rẹ naa nilo lati pari gbogbo rẹ, ki wọn too bẹrẹ igbẹjọ.

“Ẹlẹẹkeji, lai ni i fi ti abosi si i, gbogbo awọn ti wọn wa pẹlu oloogbe, gbogbo awọn ti wọn wa, ti wọn si ṣe okunfa ibi ti iṣẹlẹ ọdaran naa ti waye pata ni afurasi, gbogbo wọn lo si yẹ ki wọn ti pe fun ifọrọwanilẹnuwo, to fi mọ iwọ gangan alara.

“Ẹkẹta ni pe, ti ẹri tabi ifẹsunkan lori iwa agbere si ọkọ rẹ lasiko to o loyun ba tilẹ waye, tabi ija abẹle to n figba gbogbo ṣẹlẹ, ti ko si si ẹri fun eyi lati di ija, ohun ti yoo fa eleyii ko ju ọrọ lati mọ ojulowo baba ọmọ, eyi ti ayẹwo ẹjẹ DNA nikan le fun ọ ni idalare le lori. Fun anfaani rẹ naa ni.

“Ẹlẹẹkẹrin, to ba ṣe pe Liam ni yoo jogun gbogbo dukia ọkunrin olorin to ti doloogbe yii, to si jẹ pe laarin inu ile ni nnkan to ṣokunfa iku rẹ wa, awọn ẹbi rẹ le fi apọnle bi ọ tabi ki wọn gba ẹnu ile-ẹjọ beere pe ko o ṣe ayẹwo ẹjẹ DNA, ki wọn too le fi dukia ọmọ wọn si ikawọ rẹ lorukọ Liam. Bakan naa, ayẹwo yii yoo ran awọn oluwadii lọwọ lori iṣẹ wọn. Ẹnikẹni ko si gbọdọ di iṣẹ iwadii ọlọpaa tabi ti awọn igbimọ oluwadii ti wọn gbe dide nitori iku Mohbad (Coroner), lọwọ.

“Koko karun-un ti mo fẹẹ fa yọ ni pe, ninu ohùn kan ti wọn ka silẹ, to jẹ isọrọ rẹ, ti ko ṣee fi bẹẹ gbara le pupọ, ẹsun wa lọrun rẹ pe o fẹẹ pa Mohbad. Ko sẹni to mọ boya ija lasan to maa n waye laarin lọkọ-laya ni tabi ọrọ mi-in to lagbara.

“Ẹkẹfa ni pe, ohunkohun ti yoo ba tan imọlẹ si ọrọ yii, ti yoo si wẹ gbogbo ẹsun aiṣedeede yii mọ kuro lara rẹ, ti yoo pa gbogbo ifura ti wọn n ni si ọ yii rẹ, ati lati wa idajọ ododo fun Mohbad, lo yẹ ko jẹ ọ logun, titi kan ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ DNA.

Ni ikadii, bo o ṣe n lọ siwaju, ti o n lọ sẹyin yii, to lati danu bi araalu, ati lati mu ki awọn ọdọ tinu n bi ta ko ileeṣẹ ọlọpaa ati ijọba lori ọrọ yii. Laipẹ yii lawọn eeyan yoo sọ pe awọn alagbara kan ni wọn wa lẹyin rẹ, ti wọn n daabo bo ọ. Ẹni ọhun ko si le lagbara ju awọn eeyan ti wọn ni ipinnu lọ.

Emi ni, Yọmi Fabiyi, oṣere tiata, aṣoju ajafẹtọọ ọmọniyan, ati ọkan pataki nileeṣẹ to n ja fẹtọọ eniyan ti ki i ṣe ti ijọba, iyẹn Break The Silence Foundation”.

Bayii ni Yọmi pe akiyesi, ti o si tun fun Wumi nimọran toun ti ikilọ lori ohun ti yoo pana ẹjọ ojoojumọ to n waye ninu ẹbi wọn, latigba ti ọkọ rẹ ti ku loṣu Kẹsan-an, ọdun 2023.

Leave a Reply