Ọlọdẹ yinbọn paayan, ibi to ti fẹẹ dọgbọn ju u nu lọwọ ti tẹ ẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Rogbodiyan nla bẹ silẹ niluu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nigba tawọn araalu fọn sita pe awọn ko ni i gba ki awọn ọlọpaa mu ọkunrin ọlọdẹ kan to yinbọn paayan lọ.

Bi ki i baa ṣe pe awọn ọlọpaa tete debi iṣẹlẹ naa, o ṣee ṣe ki awọn ọdọ ti inu n bi lu ọkunrin ọlọdẹ naa pa.

Ni nnkan bii aago mẹta idaji ọjọ naa la gbọ pe ọlọdẹ yii yinbọn pa ọkunrin kan lagbegbe Láticó, niluu Iwo, lasiko to si n gbiyanju lati ju oku naa sinu igbo ni ẹnikan ka a mọbẹ.

Ẹni yii la gbọ pe o pariwo sita ti awọn araalu fi jade, lẹyin naa lawọn kan sare pe awọn ọlọpaa, ti wọn si mu ọkunrin ọlọdẹ naa lọ si agọ wọn.

Eleyii lo bi awọn ọdọ kan ninu ti wọn fi bẹrẹ ifẹhonu han, wọn dana sun taya si ojuupopo, ọpọlọpọ awọn awakọ ni wọn ko si raaye kọja.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ajọ sifu difẹnsi l̀’Ọṣun, Kehinde Adeleke, ṣalaye pe lẹyin ti awọn ọlọpaa gbe ọkunrin naa lọ tan ni wahala naa bẹrẹ.

O ni awọn sifu difẹnsi atawọn agbofinro yooku ni wọn ṣiṣẹ papọ lati ri i pe alaafia pada si agbegbe ọhun.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ọkunrin ọlọdẹ naa ti wa lakolo awọn, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ọpalọla ṣalaye pe iṣẹlẹ ọhun ko dun mọ ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun ninu rara, nitori lati oṣu Keji, ọdun yii, lawọn ti n pariwo pe awọn ọdẹ atawọn ẹṣọ alaabo abẹle ko gbọdọ lo ibọn mọ.

O parọwa si awọn eeyan ilu Iwo atawọn mọlẹbi oloogbe lati ma ṣe ṣedajọ lọwọ ara wọn, ki wọn faaye gba awọn ọlọpaa lati ṣiṣẹ wọn lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply