Bassirou, Aarẹ tọjọ ori rẹ kere ju lorileede Senegal ti gori aleefa

Faith Adebọla

Ni bayii, Aarẹ tuntun lorileede Senegal, Ọgbẹni Bassirou Diomaye Faye, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) pere, ti gori aleefa, gẹgẹ bii alakooso tọjọ ori rẹ kere ju lọ ninu itan iṣejọba orileede naa.

Nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni wọn ṣebura fun un ni agbegbe Diamniadio, to wa nitosi Dakar, ti i ṣe olu-ilu orileede Senegal.

Ṣaaju ni Bassirou ti gbegba oroke ninu eto idibo to waye lorileede naa lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, nigba to fẹyin aarẹ to wa lori aleefa to n dije fun saa kẹta rẹ, Ọgbẹni Macky Sall, janlẹ pẹlu ọpọlọpọ ibo to fi gbọọrọ-gbọọrọ tayọ tiẹ.

Bẹẹ si ree, ahamọ ọgba ẹwọn ni Aarẹ tuntun yii ti wa fun ọpọlọpọ oṣu, latari bi iṣakoso Sall ṣe sọ ọ satimọle fun ẹsun ṣiṣe atako sijọba, ati kiko awọn eeyan jọ lati da ilu ru.

Ọkunrin naa ko lanfaani lati ṣeto ipolongo ati kampeeni, bo tilẹ jẹ pe o ti gba fọọmu lati dije ko too di pe wọn ju u satimọle. Ko si ju ọsẹ meji pere ti eto idibo sipo aarẹ yoo waye ni aarẹ ana, Macky Sall, tu oun ati Ousmane Sonko silẹ lahaamọ, o fun wọn ni oore-ọfẹ aanu oṣelu, amọ Bassirou lawọn araalu fibo gbe sipo aarẹ.

Ninu ọrọ akọsọ rẹ to bawọn eeyan orileede naa sọ lẹyin ti wọn bura fun un, Aarẹ Bassirou Faye ni ileri toun ran’nu mọ ju lọ fawọn eeyan ni lati ṣe atunto orileede naa, koun si mu igba ọtun wa, o ni lori eyi loun yoo ṣiṣẹ le lẹyẹ-o-sọka, awọn eeyan yoo si ri iyatọ rere.

Iyawo meji ni Aarẹ to jẹ ẹlẹsin Musulumi yii ni, awọn mejeeji naa ni wọn si wa lẹgbẹẹ ọtun ati osi rẹ gbagbaagba nigba ti wọn n ṣebura wọle fun un.

Ẹ oo ranti pe ọpọ ọdun ni orileede Senegal, to jẹ ọkan lara awọn orileede Iwọ-Oorun ilẹ Afrika, West Africa, bii ti Naijiria, fi wa labẹ ijọba ologun, ti wọn si n ti ọwọ ologun kan bọ si omi-in, ki wọn too bẹrẹ eto ijọba demokiresi lọdun diẹ sẹyin.

Pẹlu idunnu lawọn eeyan orileede Senegal fi tu yaayaa jade lati ṣayẹsi Aarẹ tuntun yii lasiko ibura rẹ, ti wọn si n foju sọna fun igba ọtun.

Leave a Reply