Awọn ajinigbe ji arinrin-ajo mẹfa gbe ni aala ipinlẹ Ondo ati Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn afunrasi ajinigbe kan ti wọn ko ti i mọ ti ji awọn arinrin-ajo mẹfa gbe ni ọna to lọ lati ilu Akurẹ si Ado-Ekiti lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ yii.

Awako kan tọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe ni deede aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni wọn ji awọn eeyan naa to n lọ lati ilu Akurẹ si Ado-Ekiti, ti wọn si dari wọn sinu igbo.

Awọn ajinigbe yii la gbọ pe wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro loriṣiiriṣii, ti wọn si ṣe akọlu si ọkọ akero meji ni ojuko kan ti ko dara ni oju ọna naa. Ibi ti wọn ti da wọn lọna yii sun mọ aala ipinlẹ Ekiti ati Ondo, agbegbe naa si jẹ ibi kan ti awọn eeyan maa n bẹru.

ALAROYE gbọ pe inu ọkọ kekere elero mẹfa meji lawọn eeyan naa wa nigba ti awọn ajinigbe naa ṣakọlu si wọn, ti wọn si ko mẹfa ninu awọn to wa ninu ọkọ naa lọ sinu igbo, ṣugbọn ọkan lara awọn dẹrẹba ọkọ naa raaye sa mọ wọn lọwọ.

Dẹrẹba yii ṣalaye pe awọn ọkọ meji ti wọn ti ji awọn eeyan ko yii ni wọn fi dabuu ọna, ti wọn si ṣilẹkun wọn silẹ gbaragada. Eyi lawọn ero to n kọja laaarọ ọjọ keji ri ti wọn fi mọ pe wọn ti ji awakọ atawọn ero inu ọkọ naa gbe.

Titi digba ta a pari akojọpọ iroyin yii, awọn ajinigbe yii ko ti i kan si awọn mọlẹbi to wa lakata wọn lati mọ iye ti wọn fẹẹ gba.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ijinigbe naa, Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ṣugbọn ko si agọ ọlọpaa kankan nipinlẹ Ekiti ti wọn ti fi iṣẹlẹ naa to wọn leti.

 

O ṣalaye siwaju pe ohun to fa a ni pe iṣẹlẹ naa ko ṣẹlẹ nipinle Ekiti, aala ipinlẹ Ondo ati Ekiti lo ti ṣẹlẹ.

Leave a Reply