Korona pada de! O paayan meji l’Ogun, awọn mẹẹẹdogun mi-in tun fara ko o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Laarin ọsẹ mẹta si asiko yii, eeyan meji ni arun aṣekupani Korona to tun rapala wọle ti pa nipinlẹ Ogun, bẹẹ ni eeyan mẹẹẹdogun mi-in naa si tun ti fara ko kinni ọhun gẹgẹ Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ yii, Dokita Tomi Coker, ṣe ṣọ.

Atẹjade kan ti kọmiṣanna naa fi sita lo ti ṣalaye pe eeyan mẹrin lo wa nibudo itọju awọn onikorona naa bayii, bẹẹ, ko seeyan nibẹ mọ latigba ti ọwọja kokoro buruku naa ti lọ silẹ, ko too tun di pe o yọju de fun igba kẹta.

Lori ohun to fa a ti Korona fi tun raaye wọle sipinlẹ Ogun, Dokita Coker ṣalaye pe ijọba ibilẹ mẹjọ nipinlẹ Ogun lo jẹ pe ẹnu ibode ni wọn, ti wọn paala pẹlu awọn ilu mi-in, tawọn eeyan si n gbabẹ wọlẹ sipinlẹ Ogun.

Lati dẹkun itankalẹ Korona yii, awọn alakalẹ ọna teeyan fi n gbogun ti i ni wọn tun ni kawọn araalu pada si. Ọwọ fifọ deede, lilo ibomu, titakete sira ẹni, lilo nnkan ifọwọ apakokoro (sanitaisa), yiyago fun awujọ elero pupọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn ni ijọba ipinlẹ Ogun n palẹmọ ayẹwo lawọn ijọba ibilẹ marun-un ti i ṣe Guusu Abẹokuta, Ado-Odo/Ọta, Ikẹnnẹ, Ọbafẹmi Owode ati Ṣagamu.

Bakan naa ni ijọba Ogun rọ awọn eeyan lati gba abẹrẹ ajẹsara to n dena Korona, wọn ni ko lewu rara, o si daa gan-an lati gbogun ti kokoro aṣekupani naa.

Wọn tun rọ awọn olori awujọ, awọn olori ijọ ati ẹni gbogbo to ba jẹ aṣiwaju lati jẹ kawọn eeyan wọn mọ pe atẹgun Koro tun ti n fẹ kaye, ki kaluku mu ilera rẹ ni pataki, ki wọn ma ṣe sọ pe irọ nijọba n pa.

Leave a Reply