Awọn ajinigbe ji ondupo alaga kansu gbe ni Ilọrin, miliọnu marun-un ni wọn n beere

Ibrahim Alagunmu,  llọrin

Awọn ajinigbe ji Iyemọja gbe ni Ilọrin, wọn n beere fun miliọnu marun-un owo itusilẹ

Hon. Ọlamilekan Yusuf ti ọpọ eeyan mọ si Iyemọja lawon ajinigbe ti gbe lọ nile rẹ to wa ni Mandi, lagbegbe Okoolowo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ lẹnu iyawo arakunrin ọhun, Arabinrin Nafisat, ni ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti ọkọ oun n wọle bọ lati igboro, bo ṣe si geeti tan, njẹ ko gbe ọkọ wọle ni awọn ajinigbe naa ṣe akọlu si i. Iyaale ile yii ni wọn lu ọkọ oun lalubami, wọn si n rọjo ibọn ki wọn too ri ọkọ ohun gbe lọ.

Ni bayii, awọn ajinigbe naa to n sọ ede Hausa ti n beere fun miliọnu marun-un naira, owo itusilẹ.

Obinrin naa ni Nafisat awọn ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, wọn si ṣeleri pe awọn yoo gbiyanju agbara awọn lati doola ẹmi arakunrin ọhun

 

Leave a Reply