Mọrufu jale l’Ekiti, l’adajọ ba sọ ọ sẹwọn

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

Ile-ẹjọ alagbeeka kan ti wọn fijokoo ẹ si agọ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki Ọgbẹni Azeez Marufu maa lọọ jaye ori ẹ lgba ẹwọn to wa ni Ado-Ekiti na, latari ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an.

Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ ni ipinlẹ Ekiti wa ninu iyanṣẹlodi lati ọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, igbesẹ yii waye pẹlu ifikunluku laarin awọn lọpaa ati awọn Majisireeti to wa nipinlẹ naa.

 Wọn ṣalaye pe awọn ọlọpaa ni ahaamọ awọn ti kun fọfọ fawọn afurasi ọdaran to yẹ kawọn ti foju wọn bale-ẹjọ, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe latari iyanṣelodi ọhun, eyi lo mu ki wọn ṣeto igbẹjọ akanṣe si teṣan awọn ọlọpaa ọhun ki awọn afurasi arufin naa le ri idajọ ododo gba.

Inu ọgba ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’opopona to lọ si Iyin-Ekiti ni wọn fi ijokoo wọn si, ibẹ si ni igbẹjọ ti waye.

Ile-ẹjọ naa, eyi ti Onidaajọ AbdulHamid Lawal ṣe akoso rẹ, paṣẹ pe ki Ọgbẹni Marufu, eni ọgbọn ọdun, naa ṣi wa lọgba ẹwọn na lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an titi ti wọn yoo fi ri amọran gba latọdọ ajọ to n gba adajọ lamọran (Department of Public Prosecution) DPP.

Agbefọba kootu naa, Samson Osubu, sọ pe lọjọ kẹjọ, oṣu karun-un, ọdun yii, ni wọn mu afurasi ọdaran naa pe o ja Ọgbẹni Alakofa Isaac lole ọọdunrun naira, to si fibọn gba ọkada ọkunrin ọhun pẹlu ibọn ilewọ kan to mu dani.

Gbogbo sun wọnyi ni agbefọba naa sọ pe o ta ko iwe ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ekiti n lo, o si tun bẹ ileẹjọ naa pe ki wọn foun laaye diẹ lati ko awọn ẹlẹrii wa sile-ẹjọ, o si rọ ile-ẹjọ naa lati fi afurasi yii pamọ sọgba ẹwọn na.

Lọgan ni Adajọ AbdulHamid faṣẹ si ibeere olupẹjọ, o ni ki wọn taari olujẹjọ naa si ọgba ẹwọn Ado-Ekiti titi di ọgbọn ọjọ, oṣu kẹfa, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

Leave a Reply