Stephen Ajagbe, Ilorin
Lẹyin ọjọ kan tawọn ajinigbe ji Hakeem Ojo pẹlu baba agbalagba kan lọna Ira si Ọffa, nijọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara, awọn kan ti wọn fura si pe wọn jẹ Fulani darandaran tun ti ji Julius Ọlarewaju gbe, ti wọn si yinbọn fun ẹni keji to gbiyanju lati sa lọ, Jacob Ọlarewaju, lọna Obbo-Aiyegunle si Osi, nijọba ibilẹ Ekiti.
ALAROYE gbọ pe Ọgbẹni Jacob Ọlarewaju to jẹ oṣiṣẹ-fẹyinti ileewe girama Federal Government College, to wa niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ṣi wa nilewosan to ti n gba itọju latari ọta ibọn to ba a.
Ilu Omu-Aran gan-an ni wọn lawọn mejeeji n lọ lọjọ naa lati ṣabẹwo si ẹbi wọn kan to n wa nilewosan tawọn ajinigbe naa fi da wọn lọna.
Bawọn agbebọn naa ṣe ya bo wọn ni wọn gbe Julius loju–ẹsẹ, ṣugbọn Jacob gbiyanju lati sa wọnu igbo, eyi mu ki wọn yinbọn fun un. Toun pẹlu ọta ibọn to ba a, o pada mori bọ lọwọ awọn ajinigbe naa.
Akọroyin wa gbọ pe wọn ṣi n wa Julius titi di aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, awọn ajinigbe naa ko si ti i kan si mọlẹbi rẹ lati mọ ohun ti wọn fẹẹ gba.