Awọn ajinigbe ji oniṣowo epo bẹntiroolu n’Iṣan-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Lẹyin oṣu mẹta tawọn ajinigbe kan ji oloye ẹgbẹ awọn oniṣowo epo bẹntiroolu niluu Ado-Ekiti, iyẹn Alhaji Suleiman Akinbami, wọn tun ti ji ojugba rẹ niluu Iṣan-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, Ọgbẹni Itakọrọde Adebayọ.

Itakọrọde ni alakooso agba ileepo Prosperous Filling Station to wa ni IanEkiti  to jẹ ilu abinibi Gomina Kayọde Fayẹmi.

ALAROYE gbọ pe alẹ Ọjọbọ, Tọsidee  ana, lawọn ẹruuku ọhun ti wọn to meje ya bo ilu naa, ti wọn si da ibọn bolẹ ki wọn too gbe Adebayọ lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ di akoko yii.

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe nnkan bii aago meje alẹ lawọn ajinigbe ọhun ti wọn gbe ọkada bii mẹfa wọ ilu naa lati inu igbo. Lẹyin ti wọn si fibọn ṣeru ba awọn eeyan ni wọn gbe oniṣowo ọhun lọ.

Abutu ni ni kete tawọn ọlọpaa gbọ ni wọn ti ya bo agbegbe naa pẹlu ikọ Amọtẹkun atawọn ọdẹ, ti wọn si n wa gbogbo inu igbo kiri lati doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe, kọwọ si le tẹ awọn ọdaran to ṣiṣẹ laabi ọhun.

O waa ni ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti tun ti kan si awọn ọlọpaa ipinlẹ to paala pẹlu Ekiti lati ri i pe wọn wa awọn eeyan naa lawaari.

Leave a Reply