Awọn ajinigbe wọ aṣọ ṣọja wa s’Ọbada-Oko, wọn ji ọmọ ọdun mẹtala gbe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọkan awọn eeyan ko ti i fi bẹẹ balẹ lasiko yii l’Ọbada-Oko, nipinlẹ Ogun, pẹlu bawọn agbebọn kan ṣe ya wọ ibẹ lalẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹwaa,oṣu kẹrin yii, ti wọn gbe ọmọ ọdun mẹtala kan torukọ ẹ n jẹ Gbọlahan Ajibọla, lọ.

Ẹsteeti kan, Destiny Estate, lawọn ajinigbe ti wọn wọṣọ ṣọja naa lọ. Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni wọn de ọkan ninu awọn ile to wa laduugbo naa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera.

Iya kan ati ọmọ rẹ ni wọn n ti ode bọ, wọn fẹẹ wọle wọn lalẹ ọjọ naa ni. Ọmọ-ọmọ iya naa ni Gbọlahan ti wọn gbe lọ yii, ọmọ ọdun mẹtala naa fẹẹ ṣi geeti fun iya rẹ ati iya iya rẹ ki wọn le gbe mọto wọle ni.

Ṣugbọn bawọn iya ṣẹ n paaki lawọn agbebọn wọnyi de, n ni wọn ba gbe Gbọlahan ju sọkọ, wọn fẹẹ maa gbe e lọ.

Iya iya Gbọlahan, Victoria Felix, ṣalaye pe oun di ọkan ninu awọn agbebọn naa mu ki wọn ma baa gbe Gbọlahan lọ, o ni ṣugbọn niṣe ni wọn wọ oun nilẹ tuurutu, ti wọn si tun bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ.

Mama naa sọ pe kawọn ajinigbe mẹrin naa too gbe Gbọlahan lọ ni wọn ti kọkọ gba baagi oun ati iya rẹ, wọn mu foonu Gbọlahan ati ti iya rẹ lọ pẹlu.

Ni bayii ṣa, miliọnu lọna aadọta naira ( 50m) lawọn ajinigbe naa lawọn fẹẹ gba kawọn too tu ọmọ yii silẹ, wọn ni afi ko pe dandan.

Awọn ara agbegbe naa tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn paapaa sọrọ, wọn ni ijọniloju lo jẹ pe Ọbada-Oko, ilu alaafia to wa nijọba ibilẹ Ewekoro, yoo koju ijinigbe bii eyi, to bẹẹ to jẹ ko sẹni to foju kan oorun lalẹ ọjọ naa ati lẹyin ẹ paapaa, ohun to tumọ si ni pe kalara o ṣọra.

ALAROYE gbiyanju lati ba Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ipe naa ko kẹsẹjari.

Leave a Reply