Adewumi Adegoke
Afi ki onikaluku wọle adura bayii pe k’Ọlọrun maa ṣọ wa o, ka ma ko sọwọ awọn ajinigbe. Awọn olubi ẹda naa ti gbe ara mi-in yọ bayii o, owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ paarọ awọ rẹ nilẹ wa ti ẹnikẹni ko ti i maa na ni awọn ika eeyan naa n beere lọwọ awọn ti won ji gbe. Wọn ni bi wọn ko ba pese owo naa, wọn ko ni i kuro lakata awọn.
Awọn mẹrin ni wọn ji gbe labule kan ti wọn n pe ni Kolo, to wa nijọba ibilẹ Gusau, nipinlẹ Zamfara, gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe ṣalaye. Ọmọde meji, obinrin kan ati ọkunrin kan lo wa ninu awọn ti wọn ji gbe yii. Miliọnu mẹwaa Naira ni wọn ni awọn yoo gba fun owo itanran. Eyi to si buru nibẹ ni bi wọn ṣe ni awọn ko fẹ owo ilẹ wa ta a n na tẹlẹ, tuntun ti wọn ṣẹṣẹ paarọ awọ rẹ yii ni wọn gbọdọ ko wa fun awọn.
Ọkan ninu awọn ọmọ abule naa, Mohammed Ibrahim, ṣalaye pe miliọnu mẹwaa Naira ti wọn lawọn maa gba ki wọn too tu awọn eeyan naa silẹ lawọn kọko n bẹbẹ fun pe ki wọn din in ku, nitori ko sibi tawọn ti fẹẹ ri aduru owo bẹẹ. Nigba ti awọn si bẹ wọn ti wọn gba lati gba miliọnu marun-un ni awọn eeyan abule naa n mura lati tu owo ọhun jọ, ki wọn le lọọ ko o fun wọn, ki wọn si gba awọn eeyan to wa lakata wọn silẹ.
Afi bi awọn ajinigbe ọhun ṣe tun ran oniṣẹ pada si wọn pe awọn ko gba owo Naira ti a n na tẹlẹ o, owo tuntun tijọba ṣẹṣẹ paarọ awọ rẹ lawọn fẹẹ gba. Wọn ni niṣe lawọn maa toju awọn eeyan ti wọn ji gbe yii pamọ sọdo awọn titi ti owo tuntun naa yoo fi jade sita ninu oṣu Kejila ọdun yii.