Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn orileede yii, ‘The Nigerian Correctional Services’ ẹka tipinlẹ Eko ti sọ pe inu ọgba ẹwọn awọn ọkunrin lawọn maa ju Ọgbẹni Idris Okunẹyẹ, ẹni tawọn eeyan mọ si Bobrisky si, ki i ṣe inu ọgba ẹwọn awọn obinrin rara, nitori pe oun funra rẹ ti jẹwọ ni kootu pe ọkunrin pọnbele loun, oun ki i ṣe obinrin.
Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn, ẹka tipinlẹ Eko, to fidi ọrọ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lẹyin ti wọn dajọ Bobrisky tan sọ pe ko si nnkan aburu kan to maa ṣe Bobrisky lọgba ẹwọn awọn, nitori pe awọn maa pese aabo fun un ni gbogbo igba to fi maa wa lọgba ẹwọn ọhun, ti ko si ni i si ẹnikẹni to maa halẹ mọ ọn tabi fi ibalopọ akọ s’akọ lọ ọ.
O ni, ‘Ko sidii meji ta a ṣe maa ju u sẹwọn ọkunrin ju pe ni gbogbo asiko to fi n jẹjọ nile-ẹjọ ọhun, ọkunrin ni Bobrisky n pe ara rẹ, ko sọ pe obinrin loun rara, a ko le ju u sọgba ẹwọn tawọn obinrin wa, ọgba ẹwọn tawọn ọkunrin wa la maa ju u si, ṣugbọn a maa pese aabo fun un ti aburu kankan ko ni i ṣe e ni gbogbo asiko to fi maa wa lọdọ wa’’.
Tẹ o ba gbagbe, ẹwọn oṣu mẹfa lai si anfaani owo itanran ni Onidaajọ Abimbọla Awogbọrọ ti ile-ẹjọ giga to wa ni Ikoyi, niluu Eko, ju Idris Okunlẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky si, nigba ti idajọ waye lori ẹsun ṣiṣẹ owo ilẹ wa baṣubaṣu ti wọn fi kan an waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ ni Adajọ Awogbọrọ beere lọwọ Idris, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, to maa n mura bii obinrin, to si ti fẹrẹ paarọ gbogbo ẹya ara rẹ si ti obinrin tan, sọ pe ọkunrin ni oun, oun ki i ṣe obinrin.
Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ti wọn mu-un gan-an ni adajọ ni ki ẹwọn oṣu mẹfa naa bẹrẹ.