Baba Akintoye ati Sunday Igboho ti sọrọ: Awa o mọ nnkan kan nipa awọn to fẹẹ gbajọba n’Ibadan o

Bo tilẹ jẹ pe ariwo pe ọmọ ẹgbẹ ajijagbara fun ominira Yoruba ti wọn n pe ni Yoruba Nation, ni awọn eeyan n pe awọn janduku to ya wọ ileejọba to wa ni Agodi, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ni awọn fẹẹ gbakoso ibẹ, pẹlu bi wọn ṣẹ n gbiyanju lati fi asia wọn lelẹ nibẹ lọjọ kẹtala, oṣu yii, Olori awọn to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti sọ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa awọn eeyan naa. Bakan naa ni ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho, naa ni oun ko lọwọ si gbogbo ohun ti awọn eeyan naa ṣe, bẹẹ loun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Ninu fọran ti Oloye Igboho fi ranṣẹ si ALAROYE lori iṣẹlẹ naa, nibi ti Ọjọgbọn Akintoye ati oun paapaa ti sọrọ ni Olori Ilana Oodua, Ọjọgbọn Akintoye ti sọ pe, ‘‘Oloye Igboho pe mi laipẹ yii pe awọn ọmọ Dupẹ Onitiri ti ko ara wọn jọ s’Ibadan. Emi ro pe nnkan kan n ṣe ọmọbinrin ti wọn n pe ni Onitiri yẹn, ṣugbọn ti nnkan kan ba tilẹ waa rọ lu ọmọbinrin naa, ṣe nnkan tun rọ lu awọn to n tẹle e naa ni. Awọn arabinrin wa ati arakunrin wa ni wọn, ṣugbọn nnkan ti mo ro ni pe ko si ohun to n ṣe wọn, awọn kan lo wa nibi kan to n ti wọn lẹyin lati lọọ ṣe awọn ohun ti wọn n ṣe yii lati da ija ominira fun orileede Yoruba ru. Mo si gbagbọ pe awọn kan lara wa ti wọn n ṣọrẹ awọn Fulani, ti awọn Fulani n kowo fun pe ki wọn lọọ da Yoruba Nation ru, awọn to da Yoruba World Congeress ru lọjọsi, ti wọn fi n sọ pe awọn lawọn ni Yoruba Congress, pe ki i ṣe awa ti a da a silẹm awọn lo wa nidi gbogbo wahala yii. ‘‘Awọn ti ko fẹ ki Yoruba roju, ki wọn raaye ni Naijiria, ka maa ṣeru Fulani lọ laelae. Awọn ti wọn ti n ṣẹru Fulani lati igba Babangida ati Abacha, ara wọn ni awọn ti wọn ko awọn Onitiri jọ ti wọn n lo wọn bayii.

‘‘Mo fẹẹ sọ fun awọn eeyan wa, ẹyin ti ẹ n tẹle Onitiri, ẹ pada, owo to n gba lọwọ awọn Fulani, ẹ o le ri i gba. O fẹẹ di olowo bii ti ọkọ rẹ Abiọla ni, ẹ pada lẹyin rẹ, ko si nnkan to fẹẹ ṣe fun Yoruba ju pe o fẹ da ijangbara Yoruba ru, o feẹ ri i daju pe Yoruba ko kuro ni Naijiria, o fẹẹ ri i pe Yoruba yoo maa ṣeru awọn Fulani laelae. Pe ko si nnkan ti awọn Fulani le ṣe, ki wọn maa pa awọn ọba wa, ki wọn maa pa awọn ọmọ to n lọ sileewe, a ko ni i laya lati sọ pe a maa kuro ni Naijiria. Nnkan to wa nidii ọrọ yii niyẹn.  Ko si nnkan kan to wa nibẹ, wọn ko jijagbara fun Yoruba, wọn n ṣe lodi si Yoruba ni, mo sọ fun yin, ẹ kuro lẹyin rẹ’’… Bẹẹ ni Ọjọgbọn Akintoye sọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Oloye Sunday Igboho sọ pe, ‘’Mo ki gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye, Emi Oloye Sunday Adeyẹmọ ko mọ nnkan kan nipa ohun to ṣẹlẹ niluu Ibadan, koda, mi o mọ awọn to ṣe e. Ti emi ba fẹẹ ṣẹ rally tabi ipolongo fun Yoruba Nation, awa maa ti sọ ọ ṣaaju, a maa sọ fun gbogbo awọn oniroyin, awọn baba wa Banji Akintoye naa aa ti sọ ọ, a a si jọ maa fọwọ sowọ pọ ti gbogbo wa ba n ṣe e. Ṣugbọn ohunkohun ti wọn ba n da ṣe, boya wọn lọọ doju ija kọ ijọba ni o, tabi wọn lọọ koju ija si baraaki ọlọpaa tabi baraaki ṣọja, emi o mọ ohunkohun nipa rẹ’’. Bayii ni Oloye Sunday Igboho sọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu yii, ni ọrọ di bo o lọ o yago ni sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Agodi, niluu Ibadan, nibi ti awọn janduku kan ti wọn pera wọn ni ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation ti di ihamọra, ti wọn ni awọn ti gbajọba ilẹ Yoruba, awọn si fẹẹ ta asia orileede awọn si ileejọba.

Lasiko naa ni awọn atawọn agbofinro kọju ija sira wọn, ti wọn si mu awọn kan balẹ ninu wọn.

Leave a Reply