Ọwọ tẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa atawọn marun-un mi-in ti wọn ji ẹrọ tiransfọma gbe l’Abuja

Adewale Adeoye

Oṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa kan atawọn ọrẹ rẹ marun-un lọwọ ọlọpaa agbegbe Mapape, niluu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa ti tẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii. Ẹsun tawọn agbofinro ọhun fi kan wọn ni pe wọn lẹdi apo pọ laarin ara wọn lati ja ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna fawọn araalu ọhun lole lọna ti ko bofin mu.

Awọn ọdaran ọhun tọwọ tẹ ni: Kabiru Muhammad, Aliyu Usman, Abdulmalik Alhassan, Shafiu Suleman, Suleiman Ibrahim ati Raymond Mailabari, ti gbogbo wọn pata n gbe ni Tipper-Garage, lagbegbe Mapape, niluu Abuja.

ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlam oṣu yii, ni ọwọ palaba wọn segi lasiko ti wọn  lọọ ji ẹrọ tiransfọma gbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Josephine Adeh, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu yii, sọ pe oṣiṣẹ ileeṣẹ NEPA kan, Ọgbẹni Raymond Mailabari, lo ṣaaju ikọ jaguda ẹlẹni marun-un naa lọ sibi ti wọn ti ji ẹrọ tiransfọma naa gbe kọwọ too tẹ wọn.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lọ bayii pe, ‘‘Awọn araalu kan ti wọn mọ nipa iṣẹ ti ko bofin mu  tawọn ọdaran ọhun n ṣe lagbegbe naa lo waa fọrọ ọhun to wa leti ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii. A tete lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, a fọwọ ofin mu awọn ọdaran naa lasiko ti wọn n ji ẹrọ tiransfọma naa gbe, ọdọ awọn ọlọpaa ni wọn ti jẹwọ pe loootọ, awọn lawọn maa n ji ẹrọ tiransfọma agbegbe naa gbe nigba gbogbo, kọwọ too tẹ wọn.

Alukoro ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply