O ma ṣe o, kọntena re bọ sori ọkọ ayọkẹlẹ l’Alapẹrẹ, obinrin kan ku loju-ẹsẹ

Faith Adebọla

Ogun a-jade-i-wọle ti ja obinrin kan tẹnikan ko ti i mọ orukọ rẹ bayii, latari bi kọntena kan ṣe re bọ lẹyin ọkọ ajagbe Mark ti wọn so o mọ, niṣe lo ja bọ lu ọkọ ayọkẹlẹ tobinrin naa wa ninu rẹ, ọwọ ẹyin ọkọ ọhun lo jokoo si, kọntena naa si pinrin rẹ mọbẹ ni, o ku patapata.

Adebayọ Taofeek, to jẹ Alakooso eto iroyin ati ilanilọyẹ fun ajọ to n ri si lilọ-bibọ ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA) sọ f’ALAROYE pe adugbo NNPC, lọna to wọnu ẹsiteeti kan ni agbegbe Alapẹrẹ, l’Ogudu, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, o ni iwadii akọkọ tawọn ṣe lori iṣẹlẹ yii fihan pe ere buruku ni tirela ti kọntena naa wa lẹyin rẹ ọhun n sa, ati pe niṣe ni bireeki rẹ daṣẹ silẹ lojiji lori ere, eyi lo si ṣokunfa ijamba buruku naa.

Wọn ni nibi ti ọkọ ajagbe naa ti n ya barabara kiri ni kọntena ẹyin rẹ ti lọọ ja bọ lu ọkọ ayọkẹlẹ Nissan mọlẹ, nọmba ọkọ ayọkẹlẹ naa ni ABJ 692 BG, obinrin to doloogbe naa ati dẹrẹba lo wa ninu rẹ, amọ ori ko dẹrẹba naa yọ, wọn ni ko tiẹ fara pa rara.

Niṣe lero pe pitimu sibi iṣẹlẹ ọhun, bi wọn ṣe n kawọ mọri ni wọn n ṣedaro oloogbe, lasiko tawọn ẹṣọ LASTMA n ṣakitiyan lati fa oku rẹ yọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ to run womuwomu naa.

Wọn ni gbara ti ijamba naa ti ṣẹlẹ, ti dẹrẹba tirela oni-kọntena naa ti ri itu ti kọntena rẹ pa, niṣe loun ati ọmọọṣẹ rẹ poora bii iso, wọn sa lọ rau.

Ṣa, LASTMA ni awọn ti wọ awoku ọkọ ati tirela naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa ẹka ti Alapẹrẹ, bẹẹ ni wọn ti fa oku obinrin naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati gbe igbesẹ to yẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Nigba ti akọroyin ALAROYE debi iṣẹ̀ẹ naa lọjọ Abamẹta, Ṣatide, ọjọ kẹtala oṣu yii, kọtena naa ṣi wa nilẹẹlẹ nibẹ pẹlu ẹru to ko. Bẹẹ lawọn oyinbo Chinese kan atawọn eeyab mi-in duro ti kọtena ọhun. Gbogbo akitiyan akọroyin wa lati fọrọ wa awọn eeyan naa lẹnu lo ja si pabo, nitori wọn kọ lati ba akọroyin wa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ọga agba LASTMA, Ọgbẹni Ọlalekan Bakare Oki fi asiko yii parọwa fawọn onimọto, paapaa awọn to n wa ọkọ ajagbe lati jawọ ninu ere asapajude, tori ẹyẹ ibẹru ni i t’ọjọ.

Leave a Reply