Nnkan de! Awọn agbegbọn ya wọ sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ, wọn fẹẹ gbajọba lọwọ Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Boya ni ọkan Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, yoo ti i balẹ bayii, bẹẹ lọpọ eeyan ṣi wa ninu hilahilo ọkan titi ta a fi pari akojọ iroyin yii pẹlu bi awọn agbebọn kan ti irisi wọn ba ni lẹru gidigidi, ṣe ya wọ sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Abamẹta, Ṣatide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin yii, nibi ti ọfiisi gomina ipinlẹ ọhun wa, wọn ni lonii lawọn yoo gba ijọba ni dandan.

Awọn igiripa ọkunrin ọhun, la gbọ pe wọn wọ aṣọ awọn ọmoogun orileede yii, ti wọn si mura bii ṣọja pẹlu ojulowo ibọn awọn jagunjagun ilẹ yii, ṣugbọn aṣọ dudu ti wọn fi boju lo fi wọn han gẹgẹ bii janduku agbebọn. Bẹẹ ni wọn gbe asia nla kan lọwọ bii tawọn Boko Haraamu tabi awọn alakatakiti ajagungbalẹ agbaye.

Ko sẹni to lori laya lati koju awọn eeyan yii nigba ti wọn kọkọ de, afi CP Sunday Odukọya, ẹni to ti fẹyinti gẹgẹ bii ọga agba ọlọpaa, ṣugbọn to jẹ Oludamọran fun Gomina Makinde lori ọrọ eto aabo. Ṣugbọn gbogbo iwaasu alaafia t’ọkunrun naa n ṣe fun wọn ko wọ wọn leti rara, wọn ni dandan, afi bi awọn ba wọ inu sẹkiteriati, ti awọn si ri asia awọn mọlẹ nibẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ri asia Naijiria sinu ọgba naa gẹlẹ.

Eyi ni wọn n fa mọra wọn lọwọ ti awọn agbofinro ijọba apapọ bii ọlọpaa ati sifu difẹnsi fi de, ti awọn agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ bii Operation Burst atawọn Amọtẹkun fi pẹlu wọn. Awọn eleyii ko raaye ẹjọ ni tiwọn, niṣe ni gbogbo wọn n fija pẹẹta pẹlu awọn ẹni ọran naa bi kaluku wọn ṣe n de níjọníjọ, ti awọn agbofinro atawọn ti wọn pera wọn lajijagbara naa si bẹrẹ si i yinbọn mọra wọn kikankikan.

Ṣaaju lawọn agbofinro ti di gbogbo ọna to wọ sẹkiteriati, awọn ọkọ tabi eeyan lasan kan ko le gba ọna Agodi-Gate, Bodija, Total Garden tabi Mọkọla, de iwaju sẹkiteriati mọ nitori ogun to n lọ lọwọ lasiko naa. Niṣe ni gbogbo iwaju ile ijọba naa to maa n ro gudugudu, da wai nigba ti gbogbo awọn to n taja nibẹ sare palẹ mọ, ti kaluku si sa asala fun ẹmi ara ẹ.

Fun bii wakati kan ti wọn fi jọ dana ibọn funra wọn ya, o ṣoro lati mọ òpè yatọ si ọ̀ta laarin ìkọ agbarijọpọ awọn agbofinro, toun ti bi ikọ awọn agbofinro ṣe lo ibọn ati ado tajutaju ta a mọ si tiagaasi to, afi nigba ti awọn ṣọja de tikanra tikanra lati bareke wọn to wa ni Odógbó, laduugbo Ọjọọ, n’Ibadan, nigba naa lawọn iranṣẹ iku ọhun pẹyin da, n ni wọn ba na papa bora.

Ta o ba gbagbe, nigba kan, ninu oṣu Karun-un, ọdun 2023, lawọn agbebọn kan ti wọn sọ pe awọn n ja fun ominira ilẹ Yoruba, ya wọ inu ọgba ileeṣẹ Redio Amuludun, ti wọn si gbakoso ileeṣẹ naa ko too di pe awọn agbofinro kapa wọn, ti wọn si wọn sọ satimọle.

Ko ti i sẹni to le sọ pato iye eeyan to ku atawọn to fara pa nibi laasigbo naa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ diẹ ninu awọn afurasi arufin to ṣokunfa iṣẹlẹ Ijaya yii, niṣe ni wọn wọṣọ ọlọpaa, ti wọn si to oogun abẹnugọngọ loriṣiiriṣii mọra.

Leave a Reply