Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe awọn agbara kan to ju toun lọ lo wa nidii iṣẹlẹ aburu to ṣẹlẹ ni Lẹkki lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti awọn ọlọpaa ti dana ibọn fun awọn oluwọde ti wọn duro soju kan naa, ti mọkandinlaaadọta si ku ninu wọn, ti ọpọ ninu wọn fara pa.
Gomina ni, ‘‘Aṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun yii jẹ aṣaalẹ to lagbara ju ninu itan ilẹ wa, nigba ti awọn alagbara ti agbara wa ko ka, ti agbara wọn ju tiwa lọ waa fi itan buruku balẹ fun wa. Ṣugbọn a ṣetan lati koju rẹ, a oo si jade kuro ninu iṣoro naa gẹgẹ bii akọni ju bi a ṣe wa bayii lọ.
‘‘Mo ṣẹṣẹ pari abẹwo kaakiri awọn ileewosan ti wọn gbe awọn to fara gba ninu ijamba naa lọ ni.
‘‘Awọn mẹwaa lo wa nileewosan ijọba, mọkanla wa ni ileewosan Reddington, awọn mẹrin ti ipalara wọn ko pọ pupọ wa ni Vedic, nigba ti awọn meji mi-in wa nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri, iyẹn ẹka to jẹ pe ọwọ Ọlọrun nikan ni ẹmi wọn wa.
‘‘Awọn mẹta ni wọn ti da silẹ lọsibitu pe ki wọn maa lọ sile. A maa tẹsiwaju lati maa ṣamojuto awọn to wa nileewosan yii lati ri i pe wọn gba itọju to peye.
‘‘Gẹgẹ bii gomina, mo mọ pe gbogbo ẹbi ọrọ yii, ori mi lo wa, ṣugbon mo maa ṣiṣẹ pẹlu ijọba apapọ lati ri i pe a ridii okodoro ọrọ naa, ki a si ri i pe eto aabo to dara fẹsẹ mulẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.’’