Faith Adebọla
Agbako gidi lo ba awọn afurasi ajinigbe mẹfa kan tọwọ tẹ lagbegbe Tangaza, nijọba ibile Tangaza, nipinlẹ Sokoto, lopin ọsẹ to lọ yii, nigba tawọn araalu kọ lati fa wọn le agbofinro lọwọ, niṣe ni wọn fibinu dana sun wọn rau.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye nirọlẹ ọjọ Satide, lẹyin tawọn afurasi naa ti kọkọ ṣakọlu si agbegbe ọhun loru mọju ọjọ Satide, ti wọn si pa meji ninu awọn ti wọn ji gbe lọjọ naa.
Wọn niṣe lawọn ajinigbe naa mọ-ọn-mọ pa awọn eeyan ọhun latari bi wọn ṣe kọ lati gba owo itusilẹ, wọn lawọn fẹẹ gbẹsan bijọba atawọn ologun ṣe gbogun ti wọn lasiko yii.
Pipa ti wọn pa awọn meji yii ni wọn lo mu kawọn araalu naa fariga, lawọn fijilante ba dihamọra pẹlu awọn ẹṣọ alaabo mi-in, awọn ọlọpaa naa si tẹle wọn, wọn ya bo igbo tawọn janduku naa fi ṣe ibuba wọn.
Ṣinkun ni wọn ri awọn mẹfa mu, meji ninu wọn fẹẹ sa lọ ni wọn ba dana ibọn ya wọn, ti wọn si pa wọn loju-ẹsẹ, ni wọn ba ko awọn mẹrin to ku lọ sagọọ ọlọpaa to wa niluu naa.
Ṣugbọn ọrọ ko gba oju bọrọ nigba tawọn ọdọ atawọn obinrin ri awọn afurasi naa, wọn yari mọ awọn ọlọpaa lọwọ, pẹlu ikanra ni wọn fi taku pe dandan ni kawọn ṣedajọ oju-ẹsẹ fawọn janduku ẹda naa, wọn lawọn o le duro de ile-ẹjọ.
A gbọ pe ninu rogbodiyan naa lawọn araalu ti gba awọn afurasi ọdaran yii lọwọ ọlọpaa, wọn wọ wọn kuro lojude teṣan ọlọpaa, lẹsẹkẹsẹ si ni wọn ko koriko gbigbẹ ati igi le wọn lori, ti ina tẹle e.
Olugbe ilu Tangaza kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe “awọn araalu ti fihan pe awọn o mu ọrọ yii ni ṣereṣere wayii, afaimọ ni iru nnkan bayii ko ni i maa ṣẹlẹ kaakiri, tori awọn eeyan ti sun kan ogiri.
Iwa ọdaju tawọn janduku agbebọn naa hu lo mu kawọn eeyan yari kanlẹ. Nigba ti wọn n bẹ wọn pe ki wọn sọ iye owo ti wọn maa gba, niṣe lawọn ajinigbe naa tẹ atẹjiṣẹ ṣọwọ pe awọn o gba owo kankan, awọn maa pa awọn ti wọn mu ni, tori ijọba ti bẹrẹ si i pa awọn naa, bẹẹ ni wọn si ṣe.”
O ni eyi lo fa a to jẹ pe gbogbo arọwa ti DPO teṣan naa ati Alaga kansu ṣe fawọn araalu lati ma ṣe ṣedajọ oju-ẹsẹ ko wọ wọn leti, wọn lawọn maa dana sun teṣan ọlọpaa ọhun ni ti wọn o ba fa awọn agbebọn naa le awọn lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sokoto, ASP Sanusi Abubakar fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti ṣi n ṣe iwadii siwaju si i lori ẹ.