Awọn araalu mu afurasi ajinigbe to n ṣe bii were l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gbogbo awọn eeyan to wa lagbegbe Adebayọ, niluu Ado-Ekiti, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ya lọ sile akọku kan to wa niwaju ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti (EKSUTH), nibi ti wọn ti ni wọn ri ọkunrin agbalagba kan to jẹ afurasi ajinigbe.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ fun wa pe awọn eeyan fura si ọkunrin to n ṣe bii were fun igba diẹ ọhun, eyi lo fa a ti wọn fi lọọ ka a mọ ile na, nibi ti wọn ti ba oriṣiiriṣii nnkan bii fọto awọn eeyan, kaadi idanimọ, aṣọ atawọn nnkan mi-in to mu ifura dani.

Kia lawọn ero ibẹ ti fẹẹ kọ lu ọkunrin naa, ṣugbọn wọn pada fa a le ọlọpaa lọwọ nitori ootọ to wa ninu iṣẹlẹ naa ko ye ọpọ to wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn gbagbọ pe afurasi lọkunrin ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, fi ṣọwọ si ALAROYE lori ọrọ naa lo ti ni nnkan bii aago meji ọsan ku diẹ lawọn ọlọpaa gbọ pe awọn eeyan fẹẹ lu ọkunrin kan pa si agbegbe EKSUTH, eyi lo si jẹ ki ikọ RRS lọ sibẹ.

‘Ikọ RRS lo sare debẹ, ti wọn si gba ọkunrin na silẹ, lẹyin naa ni wọn mu un lọ si teṣan lati fọrọ wa a lẹnu wo nitori o n ṣe bii ẹni to ni ipenija ọpọlọ.

‘Awọn nnkan ti wọn ba lọwọ ẹ ni foonu meji to ti bajẹ, ìwo maaluu kan, sọwe-dowo banki Access marun-un, kaadi idanimọ mẹfa, kaadi owo banki Access, UBA, Zenith Bank ati Polaris Bank, eyi to jẹ tawọn eeyan meje.

‘Eyi ni lati fi to gbogbo eeyan leti pe ki wọn ma ti i gbe iroyin kiri pe ajinigbe lọkunrin naa, a si fi da a yin loju pe iwadii yoo de ileewosan ayẹwo ọpọlọ.

Abutu waa sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, Tunde Mobayọ, gba awọn niyanju lati maa ṣedajọ ọwọ fun ẹnikẹni, ki wọn si maa fi iwa ọdaran lagbegbe wọn to awọn agbofinro leti.

Leave a Reply