Awọn araalu n beere fun idajọ ododo lori Kabir ti ọlọpaa kan yinbọn pa l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Bi ọrọ ọlọpaa naa jẹ ẹfun tabi eedi, awọn eeyan agbegbe Ọta-Ẹfun, niluu Oṣogbo, ti sọ pe awọn ko fẹẹ mọ, afi ki ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣawari ọkan lara wọn to yinbọn pa ọkunrin agbẹkanga kan, Kabir Bapai, lagbegbe naa lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

 

 

Yatọ si Kabir ti ọlọpaa yii yinbọn pa, a gbọ pe o tun yinbọn mọ awakọ kan, Harisu Musa, nibi kan naa, eleyii to si mu ki awọn eeyan ibẹ fara ya, ti wọn si fẹhonu han loju popo.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ pe ileeṣẹ Shekeenah Zelter Global Concept, niluu Oṣogbo, ni Kabir ati Musa n ba ṣiṣẹ, ilu Igbajọ ni wọn si n lọ ti mọto akoyọyọ (truck) wọn fi yọnu soju ọna.

 

 

Nigba ti wọn duro lati ṣatunṣe ọkọ naa ni awọn ọlọpaa mẹta sọkalẹ latinu bọọsi kekere ti wọn n pe ni korope, ti wọn si n beere pe bawo lawọn eeyan naa ṣe jẹ ki mọto wọn taku soju ọna.

Alaye ni awọn yẹn fẹẹ maa ṣe ti ọkan lara awọn ọlọpaa naa fi bẹrẹ si i gba dẹrẹba ọkọ naa, Musa, loju-nimu, nigba ti inu si bi i tan lo yinbọn lu u lapa.

 

 

Iro ibọn la gbọ pe Kabir gbọ lati abẹ ibi to ti n tun ọkọ yii ṣe to fi gbori soke, inu si tun bi ọlọpaa yii nigba to ri Kabir, bẹẹ lo yinbọn lu u laya, loju-ẹsẹ niyẹn si ṣubu lulẹ, to ku.

 

Bi awọn eeyan agbegbe ọhun ṣe ya bo ibẹ niyẹn, wọn lu ọlọpaa kan ti ọwọ tẹ lara awọn mẹta ọhun lalubami, nigba ti awọn meji to ku juba ehoro.

A gbọ pe awọn ọdọ ti inu n bi naa gbe oku Kabir pẹlu ọlọpaa ti wọn mu yii lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ọta-Ẹfun. Lẹyin naa ni wọn gbe oku yii lọ si Osun State University Teaching Hospital, Oṣogbo.

 

 

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alakooso ileeṣẹ Shekeenah Zelter Global Concept ti Kabir n ba ṣiṣẹ, Agwu Uma, sọ pe ọmọ bibi ilu Bauchi ni oloogbe naa, ati pe inu oṣu keji, ọdun yii, lo darapọ mọ ileeṣẹ naa.

O ni iyawo Kabir wa ninu oyun, o si ti n mura lati lọọ mu un wa sipinlẹ Ọṣun ki ọdaju ọlọpaa yii too da ẹmi rẹ legbodo laaarọ ọjọ Ẹti.

 

 

Agwu sọ siwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ wa ẹni to ṣiṣẹ naa laarin wọn jade, ki idajọ ododo si fẹsẹ mulẹ lori iṣẹlẹ naa, o ni ibi ti ọkọ akoyọyọ naa taku si ki i ṣe ibi to ti n di awọn mọto to n lọ lọwọ rara.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ati pe idajọ ododo yoo waye lori ẹ.

Leave a Reply